11 Hílíkíyà ẹlẹ́ẹ̀kejì, Tábálíà ẹ̀kẹta àti Ṣékárià ẹ̀kẹrin, àwọn ọmọ àti ìbátan Hósà jẹ́ mẹ́talá (13) ni gbogbo Rẹ̀.
12 Ìpín wọ̀nyí ti àwọn olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà nípasẹ̀ olóyè ọkùnrin wọn, ní iṣẹ́ ìsìn fún jíjísẹ́ nínú ilé Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìbátan wọn ti ṣe.
13 Wọ́n ṣẹ́ kèké fún ẹnu ọ̀nà kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àwọn ìdílé wọn bí ọ̀dọ́ àti arúgbó.
14 Kèké fún ẹnu ọ̀nà ilà oòrùn bọ́ sí ọ̀dọ̀ Ṣélémíáyà, nígbà náà a dá kèké fún ọmọkùnrin rẹ̀ Ṣekaríáyà, ọlọ́gbọ́n onímọ̀ràn, kèké fún ẹnu ọ̀nà àríwá sì bọ́ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
15 Kèké fún ẹnu ọ̀nà ìhà gúṣù bọ́ sí ọ̀dọ̀ Obedì Édómù, kèké fún ilé ìṣúra sì bọ́ sí ọ̀dọ̀ ọmọ Rẹ̀.
16 Kèké fún ẹnu ọ̀nà ìhà ìwọ̀ oòrùn àti Ṣálélà-etí ẹnu ọ̀nà ní ọ̀nà apá òkè bọ́ sí ọ̀dọ̀ Ṣúpímì àti Hósà.Olùsọ́ wà ní ẹ̀bá Olùsọ́:
17 Àwọn ará Léfì mẹ́fà ní ó wà ní ọjọ́ kan ní ìhà ìlà oòrùn, mẹ́rin ní ọjọ́ kan ní ìhà àríwá, mẹ́rin ní ọjọ́ kan ní ìhà gúṣù àti méjì ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ní ilé ìṣúra.