20 lórí àwọn ará Éfíráímù: Hòṣéà ọmọ Áṣásíà;lorí ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè: Jóélì ọmọ Pedáyà;
21 lorí ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ní Gílíádì: Ìdó ọmọ Ṣékáráyà;lórí Bẹ́ńjámínì: Jásíélì ọmọ Ábínérì;
22 lórí Dánì: Áṣárélì ọmọ Jéróhámù.Wọ̀nyí ni àwọn ìjòyè lórí ẹ̀yà Ísírẹ́lì.
23 Dáfídì kò kọ iye àwọn ọkùnrin náà ní ogún ọdún sẹ́yìn tàbí dín nítori Olúwa ti ṣe ìlerí lati ṣe Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí iye ìràwọ̀ ojú ọ̀run.
24 Jóábù ọmọ Ṣérúyà bẹ̀rẹ̀ sí ní kàwọ́n, ṣùgbọ́n kò parí kíkà wọ́n nítorí, ìbínú dé sórí àwọn Ísírẹ́lì nipaṣẹ̀ kíka iye àti iye náà, a kò kọọ́ sínu ìwé ìtàn ayé ti ọba Dáfídì.
25 Áṣímáfétì ọmọ Ádíélì wà ní ìdí ilé ìṣúra ti ọba. Jónátanì ọmọ Úṣíà wà ní ìdí ilé ìṣúra ní iwájú agbègbè nínú àwọn ìlú, àwọn ìlètò àti àwọn ilé ìṣọ́.
26 Ésírì ọmọ kélúbì wà ní ìdí àwọn òṣìṣẹ́ lórí pápá, tí wọ́n ń ko ilẹ̀ náà.