8 Ẹ̀káàrún fún oṣù kárùn-ún, jẹ́ olórí Ṣámíhútì ará Íṣíráhì. Ẹgbàá méjìlá ọkùnrin (24,000) ní ó wà ní ìpín tirẹ̀.
9 Ẹ̀kẹfà fún oṣù kẹfà jẹ́ Írà ọmọ Íkéṣì, ará Tékóì. Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín Rẹ̀.
10 Ẹ̀kéje fún oṣù kéje jẹ́ Hélésì ará Pélónì, ará Éfíráímù. Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni o wà ní ìpín Rẹ̀.
11 Ẹ̀kẹjọ fún oṣù kẹjọ jẹ́ Ṣíbékáì ará Húṣátì, ará Ṣéráhì ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín Rẹ̀.
12 Ẹ̀kẹsàn-án fún oṣù kẹ́sàn-án jẹ́. Ábíésérì ará Ánátótì, ará Bénjámínì ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín Rẹ̀.
13 Ẹ̀kẹwàá fún oṣù kẹ́wàá jẹ́ Máháráì ará Nétófátì, ará Ṣéráhì ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín Rẹ̀.
14 Ìkọkànlá fún oṣù kọkànlá jẹ́ Bénáyà ará pírátónì ará Éfíráímù ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín tirẹ̀.