19 Àwọn ọmọ aya Hódíyà arábìnrin Náhámù:Baba Kéílà ará Gárímì, àti Ésítémóà àwọn ará Mákà.
20 Àwọn ọmọ Símónì:Ámónì, Rínà, Beni-Hánánì àti Tílónì.Àwọn ọmọ Íṣì:Ṣóhítì àti Beni-Sóhétì.
21 Àwọn ọmọ Ṣélà ọmọ Júdà:Érì baba Lékà, Ládà baba Máréṣà àti àwọn ìdílé ilé àwọn tí ń wun aṣọ oníṣẹ́ ní Bẹti-Áṣíbéà.
22 Tókímù, ọkùnrin kósébà, àti Jóáṣì àti sáráfù, olórí ní Móábù àti Jáṣúbì Léhémù. (Àkọsílẹ̀ yìí sì wà láti ìgbà àtijọ́).
23 Àwọn sì ni amọ̀kòkò tí ń gbé ní Nítaímù àti Gédérà; wọ́n sì dúró níbẹ̀ wọ́n sì ń sisẹ́ fún ọba.
24 Àwọn Ọmọ Síméónì:Némúélì, Jámínì, Járíbì, Ṣérà àti Ṣáúlì;
25 Ṣálúmù sì jẹ́ ọmọ Ṣáúlì, Míbísámù ọmọ Rẹ̀ Miṣima ọmọ Rẹ̀.