26 Ṣùgbọ́n àwọn olórí olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí wọ́n jẹ́ ará Léfì ni a yàn fún àwọn iyàrá àti àwọn àpótí ìsúra ní ilé Olúwa.
27 Wọ́n á lo gbogbo òru ní dídúró yí ilé Olúwa ká, nítorí wọ́n ní láti ṣọ́ ọ; Wọ́n sì ní àṣẹ sí kọ́kọ́rọ́ fún ṣíṣí i ní àràárọ̀.
28 Díẹ̀ wà ní ìdí ohun èlò tí à ń lò fún ìsìn ilé Olúwa; wọn a má a kàá nígbà tí wọ́n gbé e wọlé àti nígbà tí a kó wọn jáde.
29 Àwọn mìíràn ni a yàn láti bojútó ohun èlò àti gbogbo ohun èlò ilé tí a yà sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run, àti ìyẹ̀fun àti ọtí èso àjàrà àti òróró náà, tùràrí àti tùràrí òlóòórìn dídùn.
30 Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn àlùfáà ni ó ń bojútó pípo tùràrí olóòórùn dídùn papọ̀.
31 Ará Léfì tí a sọ ní Mátítíhíà, àkọ́bí ọmọkùnrin Ṣálúmì ará kórà ni a yàn sí ìdí dídín àkàrà ọrẹ.
32 Lára àwọn arákùnrin wọn kora wọn wà ní ìdí ṣísètò fún àkàrà tí a máa ń gbé sórí àga tábìlì ní ọjọjọ́ Ìsinmi.