31 Ará Léfì tí a sọ ní Mátítíhíà, àkọ́bí ọmọkùnrin Ṣálúmì ará kórà ni a yàn sí ìdí dídín àkàrà ọrẹ.
32 Lára àwọn arákùnrin wọn kora wọn wà ní ìdí ṣísètò fún àkàrà tí a máa ń gbé sórí àga tábìlì ní ọjọjọ́ Ìsinmi.
33 Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin, olórí àwọn ìdílé Léfì dúró nínú àgọ́ ilé Olúwa, wọn kò sì se lára isẹ́ ìsìn yòókù nítorí wọ́n ń se isẹ́ náà lọ́sán, lóru.
34 Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ olórí àwọn Léfì, olóyè gẹ́gẹ́ bí a ti se kọ lẹ́sẹsẹ sínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, wọ́n sì ń gbé ní Jérúsálẹ́mù.
35 Jélíélì baba Gíbíónì ń gbé ní Gíbíónì.Orúkọ ìyàwó Rẹ̀ a má a jẹ́ Mákà,
36 Pẹ̀lú àkọ́bí ọmọkùnrin Rẹ̀ jẹ́ Ábídónì, tí wọ̀nyí sì ń tẹ̀lé Ṣúrì, Kíṣì Bálì, Nérì, Nádábù.
37 Gédórì, Áhíò, Sékaráyà àti Míkílótì.