10 Ṣùgbọ́n kò pe Nátanì Wòlíì tàbí Bénáyà tàbí àwọn olórí tàbí Sólómónì arákùnrin rẹ̀.
11 Nígbà náà ni Nátanì bèrè lọ́wọ́ Bátíṣébà, ìyá Sólómọ́nì pé, “Ǹjẹ́ ìwọ kò gbọ́ pé Àdóníjà, ọmọ Hágítì ti jọba láìjẹ́ pé Dáfídì Olúwa wa mọ̀ síi?
12 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, jẹ́ kí èmi gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn bí ìwọ ṣe lè gba ẹ̀mí rẹ là àti ẹ̀mí ọmọ rẹ Sólómónì.
13 Lọ sọ́dọ̀ Dáfídì ọba, kí o sì wí fún un pé, ‘Olúwa mi ọba, ǹjẹ́ ìwọ kò búra fún ìránṣẹ́ rẹ pé, “Dájúdájú Sólómónì ọmọ rẹ ni yóò Jọba lẹ́yìn mi, yóò sì jókòó lórí ìtẹ́ mi?” Èéṣe nígbà náà tí Àdóníjà fi jọba?’
14 Níwọ̀n ìgbà tí ìwọ sì wà níbẹ̀, tí o sì ń bá ọba sọ̀rọ̀ èmi yóò wá, láti wádìí ohun tí o ti sọ.”
15 Bẹ́ẹ̀ ni Bátíṣébà lọ rí ọba ní inú yàrá rẹ̀, ọba sì gbó gidigidi níbi tí Ábíságì ará Súnémù sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún ọba.
16 Bátíṣébà sì tẹríba, ó sì kúnlẹ̀ níwájú ọba.Ọba sì béèrè pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́?”