2 Ó sì wá sí Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú ẹgbẹ́ èrò ńlá ńlá, pẹ̀lú ràkúnmí tí ó ru tùràrí, ati ọ̀pọ̀lọpọ̀ wúrà, àti òkúta iyebíye, ó sì wá sí ọ̀dọ̀ Sólómónì, ó sì bá a sọ gbogbo èyí tí ń bẹ ní ọkàn rẹ̀.
3 Sólómónì sì dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀; kò sì sí èyí tí ó ṣòro fún ọba láti ṣàlàyé fún un.
4 Nígbà tí ayaba Ṣébà sì rí gbogbo ọgbọ́n Sólómónì àti ààfin tí ó ti kọ́.
5 Oúnjẹ tí ó wà lórí i tábìlì rẹ̀, ìjókòó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti ìdúró àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti ìwọṣọ wọn, àwọn agbọ́tí rẹ̀, àti ẹbọ ọrẹ̀ sísun tí ó sun ní ilé Olúwa, kò sì sí ẹ̀mí kan nínú rẹ̀ mọ́!
6 Ó sì wí fún ọba pé, “Òtítọ́ ni ìròyìn tí mo gbọ́ ní orílẹ̀ èdè mi níti iṣẹ́ rẹ àti ọgbọ́n rẹ.
7 Ṣùgbọ́n èmi kò sì gba nǹkan wọ̀nyí gbọ́ títí ìgbà tí mo wá, tí mo sì fi ojú ara mi rí i. Sì kíyèsí i, a kò sọ ìdajì wọn fún mi; ìwọ sì ti fi ọgbọ́n àti ìrora kọjá òkìkí tí mo gbọ́.
8 Báwo ni inú àwọn ènìyàn rẹ yóò ṣe dùn tó! Báwo ni inú dídùn àwọn ìránṣẹ́ rẹ, tí wọ́n ń dúró níwájú rẹ nígbà gbogbo, tí wọ́n sì ń gbọ́ ọgbọ́n rẹ!