27 Réhóbóámù ọba sì ṣe asà idẹ ní ipò wọn, ó sì fi wọ́n sí ọwọ́ olórí àwọn olùṣọ́ tí ń sọ́ ilẹ̀kùn ilé ọba.
28 Nígbàkígbà tí ọba bá sì lọ sí ilé Olúwa Wọ́n á rù wọ́n, wọ́n á sì mú wọn padà sínú yàrá olùṣọ́.
29 Níti ìyókù ìṣe Réhóbóámù, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Júdà bí?
30 Ogun sì wà láàrin Réhóbóámù àti Jéróbóámù ní ọjọ́ wọn gbogbo.
31 Réhóbóámù sì sùn pẹ̀lú àwọn bàbá rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú wọn ní Ìlú Dáfídì. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Náámá; ará Ámónì. Ábíjà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.