1 Ó sì ṣe, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jéhù ọmọ Hánánì wá sí Bááṣà pé:
2 “Èmi ti gbé ọ ga láti inú erùpẹ̀ wá, mo sì fi ọ́ ṣe olórí Ísírẹ́lì ènìyàn mi, ṣùgbọ́n ìwọ sì rìn ní ọ̀nà Jéróbóámù, ó sì mú kí Ísírẹ́lì ènìyàn mi dẹ́ṣẹ̀, láti mú mi bínú nípa ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
3 Nítorí náà, èmi yóò mú Bááṣà àti ile rẹ̀ kúrò, èmi yóò sì ṣe ilé rẹ̀ bí ilé Jéróbóámù ọmọ Nébátì.
4 Àwọn ajá yóò jẹ ẹni Bááṣà tí ó bá kú ní ìlú, ẹyẹ ojú ọ̀run yóò sì jẹ àwọn tí ó kú ní oko.”
5 Àti ìyókù ìṣe Bááṣà, ohun tí ó ṣe àti agbára rẹ̀, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì?