43 Ó sì wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Lọ, kí o sì wo ìhà òkun, òun sì gòkè lọ, ó sì wò.”Ó sì wí pé, “Kò sí nǹkan níbẹ̀.”Ó sì wí pé, “Tún lọ nígbà méje.”
44 Nígbà keje, ìránṣẹ́ náà sì wí pé, “Àwọ̀sánmọ̀ kékeré kan dìde láti inú òkun, gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ ènìyàn.”Èlíjà sì wí pé, “Lọ, kí o sọ fún Áhábù pé, ‘Di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ, kí o sì sọ̀kalẹ̀ lọ, kí òjò ó má ba à dá ọ dúró.’ ”
45 Ó sì ṣe, nígbà díẹ̀ sí i, ọ̀run sì sú fún àwọsánmọ̀, ìjì sì dìde, òjò púpọ̀ sì rọ̀, Áhábù sì gun kẹ̀kẹ́ lọ sí Jésírẹ́lì.
46 Agbára Olúwa sì ń bẹ lára Èlíjà; ó sì di àmùrè ẹ̀gbẹ́ rẹ, ó sì ṣáré níwájú Áhábù títí dé Jésírẹ́lì.