1 Ọba 2:24-30 BMY

24 Àti nísinsìnyí, bí ó ti dájú pé Olúwa wà láàyè ẹni tí ó ti mú mi jókòó lórí ìtẹ́ baba mi Dáfídì àti tí ó sì ti kọ́ ilé fún mi bí ó ti ṣèlérí, lónìí ni a ó pa Àdóníjà!”

25 Sólómónì ọba sì pàṣẹ fún Bénáyà ọmọ Jéhóíádà, ó sì kọlu Àdóníjà, ó sì kú.

26 Ọba sì wí fún Ábíátarì àlùfáà pé, “Padà lọ sí pápá rẹ ni Ánátótì, ó yẹ fún ọ láti kú, ṣùgbọ́n èmi kì yóò pa ọ́ nísinsìn yìí, nítorí o ti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa níwájú Dáfídì baba mi, o sì ti ní ìpín nínú gbogbo ìyà tí baba mi jẹ.”

27 Bẹ́ẹ̀ ni Sólómónì yọ Ábíátarì kúrò nínú iṣẹ́ àlùfáà Olúwa, kí ó lè mú ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti sọ nípa ilé Élì ní Ṣílò ṣẹ.

28 Nígbà tí ìròyìn sì dé ọ̀dọ̀ Jóábù, ẹni tí ó ti dìtẹ̀ pẹ̀lú Àdóníjà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wà pẹ̀lú Ábúsálómù, ó sì sá lọ sínú àgọ́ Olúwa, ó sì di ìwo pẹpẹ mú.

29 A sì sọ fún Sólómónì ọba pé Jóábù ti sá lọ sínú àgọ́ Olúwa àti pé ó wà ní ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. Nígbà náà ni Sólómónì pàṣẹ fún Bénáyà ọmọ Johóíadà pé, “Lọ, kí o sì kọlù ú.”

30 Bénáyà sì wọ inú àgọ́ Olúwa, ó sì wí fún Jóábù pé, “Ọba sọ wí pé, Jáde wá.”Ṣùgbọ́n ó dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, Èmi yóò kú níhìn ín.”Bénáyà sì mú èsì fún ọba, “Báyìí ni Jóábù ṣe dá mi lóhùn.”