15 Nígbà tí ó sì dé, ọba sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Míkáyà, ṣé kí a lọ bá Ramoti-Gílíádì jagun, tàbí kí a jọ̀wọ́ rẹ̀?”Ó sì dáhùn wí pé, “Lọ, kí o sì ṣẹ́gun, nítorí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́.”
16 Ọba sì wí fún un pé, “Ìgbà mélòó ni èmi yóò fi ọ bú pé kí o má ṣe sọ ohun kan fún mi bí kò ṣe òtítọ́ ní orúkọ Olúwa?”
17 Míkáyà sì dáhùn pé, “Mo rí gbogbo Ísírẹ́lì túkáàkiri lórí àwọn òkè bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́, Olúwa sì wí pé, ‘Àwọn wọ̀nyí kò ní olúwa. Jẹ́ kí olúkúlùkù padà sí ilé rẹ̀ ní àlàáfíà.’ ”
18 Ọba Ísírẹ́lì sì wí fún Jèhósáfátì pé, “Ǹjẹ́ èmi kò sọ fún ọ pé kò fọ ire kan sí mi rí bí kò ṣe ibi?”
19 Míkáyà sì tún wí pé, “Nítorí náà gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa: Mo rí Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ogun ọ̀run dúró ní apá ọ̀tún àti ní apá òsì rẹ̀.
20 Olúwa sì wí pé, ‘Ta ni yóò tan Áhábù láti kọlu Ramoti-Gílíádì? Kí ó sì tọ ikú rẹ̀ lọ níbẹ̀?’“Ẹnìkan wí báyìí, ẹlòmíràn sì sọ mìíràn.
21 Ẹ̀mí kan sì jáde wá, ó sì dúró níwájú Olúwa, ó sì wí pé, ‘Èmi yóò tàn án.’