20 Olúwa sì wí pé, ‘Ta ni yóò tan Áhábù láti kọlu Ramoti-Gílíádì? Kí ó sì tọ ikú rẹ̀ lọ níbẹ̀?’“Ẹnìkan wí báyìí, ẹlòmíràn sì sọ mìíràn.
21 Ẹ̀mí kan sì jáde wá, ó sì dúró níwájú Olúwa, ó sì wí pé, ‘Èmi yóò tàn án.’
22 “Olúwa sì béèrè pé, ‘Báwo?’ Ó sì wí pé,“ ‘Èmi yóò jáde lọ, èmi yóò sì di ẹ̀mí èké ní ẹnu gbogbo àwọn wòlíì rẹ̀.’“Olúwa sì wí pé, ‘Ìwọ yóò tàn án, ìwọ yóò sì borí, jáde lọ, kí o sì ṣe bẹ́ẹ̀.’
23 “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ti fi ẹ̀mí èké sí ẹnu gbogbo àwọn wòlíì rẹ wọ̀nyí. Olúwa sì ti sọ ibi sí ọ.”
24 Nígbà náà ni Ṣedekíàh ọmọ Kénáánà sì dìde, ó sì gbá Míkáyàh lójú, ó sì wí pé, “Ọ̀nà wo ni ẹ̀mí Olúwa gbà lọ kúrò lọ́dọ̀ mi láti bá ọ sọ̀rọ̀?”
25 Míkáyà sì wí pé, “Ìwọ yóò rí i ní ọjọ́ náà, nígbà tí ìwọ yóò lọ láti inú ìyẹ̀wù dé ìyẹ̀wù láti fi ara rẹ pamọ́.”
26 Ọba Ísírẹ́lì sì pàṣẹ pé, “Ẹ mú Míkáyà, kí ẹ sì mú un padà sọ́dọ̀ Ámónì, olórí ìlú, àti sọ́dọ̀ Jóásì ọmọ ọba