1 Ní ìgbà tí ó pe ọ̀rìnlénírinwó ọdún l (488) ẹ́yìn ìgbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì, ní ọdún kẹrin ìjọba Sólómónì lórí Ísírẹ́lì, ní oṣù Sífì, tí ń ṣe oṣù kejì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé Olúwa.
2 Ilé náà tí Sólómónì ọba kọ́ fún Olúwa sì jẹ́ ọgọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú àti ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gíga.
3 Ìloro níwájú tẹ́ḿpìlì ilé náà, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rẹ̀, ìbú ilé náà, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti iwájú ilé náà.
4 Ó sì ṣe fèrèsé tí kò fẹ̀ fún ilé náà.