1 Ọba 8:48-54 BMY

48 bí wọ́n bá sì fi gbogbo àyà àti gbogbo ọkàn wọn yípadà sí ọ, ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn, tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ, tí wọ́n sì gbàdúrà sí ọ sí ìhà ilẹ̀ wọn tí ìwọ ti fi fún àwọn baba wọn, Ìlú tí ìwọ ti yàn, àti ilé tí èmi kọ́ fún orúkọ rẹ;

49 Nígbà náà ni kí ìwọ kí ó gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn ní ọ̀run, ní ibùgbé rẹ, kí o sì mú ọ̀ràn wọn dúró.

50 Kí o sì dáríjìn àwọn ènìyàn rẹ, tí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ; dárí gbogbo ìrékọjá wọn tí wọ́n ṣe sí ọ jì, kí o sì bá àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ wí, kí wọn kí ó lè ṣàánú fún wọn;

51 nítorí ènìyàn rẹ àti ìní rẹ ni wọ́n, àwọn ẹni tí ìwọ ti mú ti Éjíbítì jáde wá, láti inú irin ìléru.

52 “Jẹ́ kí ojú rẹ sí sí ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ, àti sí ẹ̀bẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì, kí o sì tẹ́tí sílẹ̀ sí wọn nígbà tí wọ́n bá kégbe sí ọ.

53 Nítorí tí ìwọ ti yà wọ́n kúrò nínú gbogbo orílẹ̀ èdè ayé, láti máa jẹ́ ìní rẹ, bí ìwọ ti sọ lati ọwọ́ Móṣè ìránṣẹ́ rẹ, nígbà tí ìwọ Olúwa Ọlọ́run mú àwọn baba wa ti Éjíbítì jáde wá.”

54 Nígbà tí Sólómónì ti parí gbogbo àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ yìí sí Olúwa tán, ó dìde kúrò lórí eékún rẹ̀ níwájú pẹpẹ Olúwa níbi tí ó ti kúnlẹ̀ tí ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí òkè ọ̀run