16 Nígbà náà Míkáyà dáhùn, “Mo rí gbogbo Ísírẹ́lì fọ́n káàkiri lórí àwọn òkè, bí àgùntàn tí kò ní olùsọ́. Olúwa sì wí pé, ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí kò ní ọ̀gá. Jẹ́ kí olúkúlùkù lọ sí ilé ní àlàáfíà.’ ”
17 Ọba Ísírẹ́lì wí fún Jéhóṣáfátì pé, “Ṣe èmi kò sọ fún ọ wí pé òun kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere kankan nípa mi rí, ṣùgbọ́n búburú nìkan?”
18 Mikáyà tẹ̀ṣíwájú pé, “Nítorí náà, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa: Mo rí Olúwa jòkó lórí ìtẹ́ rẹ̀ gbogbo ogun ọ̀run sì dúró lápá ọ̀tún àti lápá òsì.
19 Olúwa sì wí pé, ‘Ta ni yóò tan Áhábù ọba Ísírẹ́lì lọ sí Rámátì Giléádì kí ó sì lọ kú ikú rẹ̀ níbẹ̀?’“Èkínní sì sọ tìhín, òmíràn sì sọ tọ̀hún.
20 Ní ìparí, ni ẹ̀mí kan wá ṣíwájú, ó dúró níwájú Olúwa ó sì wí pé, ‘Èmi yóò tàn án.’“ ‘Nípa ọ̀nà wo?’ Olúwa beèrè.
21 “ ‘Èmi yóò lọ láti lọ di ẹ̀mí èké ní ẹnu gbogbo àwọn wòlíì.’ Ó wí pé.“ ‘Ìwọ yóò sì borí nínú ìtànjẹ rẹ̀ báyìí,’ ni Olúwa wí. ‘Lọ kí ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.’
22 “Bẹ́ẹ̀ ni nísinsìn yìí Olúwa ti fi ẹ̀mí èké sí ẹnu àwọn wòlíì rẹ. Olúwa sì ti sọ ibi sí ọ.”