19 Olúwa sì wí pé, ‘Ta ni yóò tan Áhábù ọba Ísírẹ́lì lọ sí Rámátì Giléádì kí ó sì lọ kú ikú rẹ̀ níbẹ̀?’“Èkínní sì sọ tìhín, òmíràn sì sọ tọ̀hún.
20 Ní ìparí, ni ẹ̀mí kan wá ṣíwájú, ó dúró níwájú Olúwa ó sì wí pé, ‘Èmi yóò tàn án.’“ ‘Nípa ọ̀nà wo?’ Olúwa beèrè.
21 “ ‘Èmi yóò lọ láti lọ di ẹ̀mí èké ní ẹnu gbogbo àwọn wòlíì.’ Ó wí pé.“ ‘Ìwọ yóò sì borí nínú ìtànjẹ rẹ̀ báyìí,’ ni Olúwa wí. ‘Lọ kí ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.’
22 “Bẹ́ẹ̀ ni nísinsìn yìí Olúwa ti fi ẹ̀mí èké sí ẹnu àwọn wòlíì rẹ. Olúwa sì ti sọ ibi sí ọ.”
23 Nígbà náà Sedékíà ọmọ Kénánà lọ sókè ó sì gbá Míkáyà ní ojú. “Ní ọ̀nà wo níi ẹ̀mí Olúwa gbà kọjá lọ kúrò lọ́dọ̀ mi láti bá ọ sọ̀rọ̀?” Ó sì bèèrè.
24 Míkáyà sì dáhùn pé, “ìwọ yóò ṣe ìwadìí ní ọjọ́ tí ìwọ yóò sápamọ́ sínú ìyẹ̀wù.”
25 Ọba Ísírẹ́lì paálásẹ pé, “Mú Mikáyà kí o sì ran padà sí Ámónì olóri ìlú àti sí Jóáṣì ọmọ ọba,