24 Míkáyà sì dáhùn pé, “ìwọ yóò ṣe ìwadìí ní ọjọ́ tí ìwọ yóò sápamọ́ sínú ìyẹ̀wù.”
25 Ọba Ísírẹ́lì paálásẹ pé, “Mú Mikáyà kí o sì ran padà sí Ámónì olóri ìlú àti sí Jóáṣì ọmọ ọba,
26 Ó sì wí pé ‘Èyí ni ohun tí ọba sọ: ẹ fi ènìyàn yìí sínú túbú kí ẹ má sì ṣe fún-un ní ohunkóhun ṣùgbọ́n àkàrà àti omi títí tí èmi yóò fi dé ní àlàáfíà.’ ”
27 Míkáyà sì wí pe, “Tí ìwọ bá padà ní àlàáfíà, Olúwa kò sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ mi.” Nígbà náà, ó sì fi kún-un pé, “Ẹgbọ́ ọ̀rọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn!”
28 Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì àti Jéhóṣáfátì ọba Júdà lọ sókè ní Rámótì Gílíádì.
29 Ọba Ísírẹ́lì sọ fún Jéhóṣáfátì pé, “Èmi yóò lọ sí ojú ìjà, ṣùgbọ́n ìwọ wọ aṣọ ìgunwà rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì pa aṣọ rẹ̀ dà, ó sì lọ sí ojú ìjà.
30 Nísinsìn yìí ọba Síríà ti pàsẹ fún àwọn olórí kẹ̀kẹ́ tí ó wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ má ṣe jà pẹ̀lú ẹnìkankan, èwe tàbí àgbà àyàfi ọba Ísírẹ́lì.”