3 Ọba dá láti ara ohun ìni rẹ̀ fun ọrẹ sísun àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ àti fún ọrẹ sísun ní ọjọ́ ìsinmi, òṣùpá tuntun àti àsè yíyàn gẹ́gẹ́ bi a ti se kọ ọ́ nínú òfin Olúwa.
4 Ó pàsẹ fún àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Jerúsálẹ́mù láti fi ìpín tí ó yẹ fún àlùfáà fún un àti àwọn ará Léfì, kí wọn kí ó lè fi ara wọn jìn fún òfin Olúwa.
5 Ní kété tí àṣẹ náà jáde lọ, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi tìfẹ́tìfẹ́ fi àkóso ti ọkà wọn, ọtí titun òróró àti oyin àti gbogbo ohun tí pápá mú jáde lélẹ̀. Wọ́n kó ọ̀pọ̀ iye, àti ìdámẹ́wàá gbogbo nǹkan.
6 Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì àti Júdà ti gbe inú àwọn ìlú Júdà pẹ̀lú mú ìdámẹ́wàá agbo ẹran àti ohun èlò àti ohun Ọ̀sìn àti ìdámẹ́wàá ti àwọn nǹkan mímọ́ tí a ti yà sọ́tọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì kó wọn jọ ní òkítì.
7 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ṣiṣe èyí ní oṣù kẹ́ta, wọ́n sì parí ní oṣù kéje.
8 Nígbà tí Heṣekáyà àti àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ wá, tí wọ́n sì rí òkítì náà, wọ́n yin Olúwa, pẹ̀lú ìbùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì.
9 Heṣekáyà bèrè lọ́wọ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì nípa òkìtì;