1 Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà mú Jehóáhásì ọmọ Jósíà wọn sì fi jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù ni ipọ̀ Baba rẹ̀.
2 Jehóáhásì sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́talélọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ni Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́ta.
3 Ọba Éjíbítì lé e kúrò lórí ìtẹ́ ní Jérúsálẹ́mù ó sì bù fún un lórí Júdà, ọgọ́rún talẹ́ńtì fàdákà (100) àti talẹ́ntì wúrà kan.
4 Ọba Éjíbítì sì mú Élíákímù, arákùnrin Jehóáhásì, jẹ ọba lórí Júdà àti Jérúsálẹ́mù, ó sì yí orúkọ Eliákímù padà sí Jéhóíákíámù, ṣùgbọ́n Nékò mú arákùnrin Eliákímù, Jehóáhásì ó sì gbé e lórí Éjíbítì.
5 Jéhóíákímù sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún méjìlá. Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.