6 Àwọn àlùfáà dúró ní àyè wọn, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Léfì ti ṣe pẹ̀lú ohun èlò orin Olúwa, tí ọba Dáfídì ti ṣe fún ìyìn Olúwa àti tí á lò nígbà tí ó dúpẹ́, wí pé, “àànú rẹ̀ sì dúró láéláé,” níwájú àwọn ọmọ Léfì, àwọn àlùfáà sì fọn ipè, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì dúró.
7 Sólómónì sì yà sọ́tọ̀ láàrin àgbàlá níwájú ilé Olúwa, níbẹ̀ sì ni ó ti se ìrúbọ ọrẹ sísun àti ọ̀rá ẹbọ àlàáfíà, nítorí pẹpẹ idẹ tí ó ti ṣe kò lè gba ọrẹ sísun, àti ọrẹ oúnjẹ, àti ọ̀rá náà.
8 Bẹ́ẹ̀ ni Sólómónì se àsè ní àkókò náà fún ọjọ́ méje àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀ àti ìjọ ènìyàn ńlá, àwọn ènìyàn láti Lébò Hámátì títí dé odò Éjíbítì.
9 Ní ọjọ́ kẹ́jọ, wọ́n sì pe ìjọ ènìyàn jọ nítorí tí wọ́n pe àpèjẹ ìyà símímọ́ ti orí pẹpẹ fún ọjọ́ méje àti àṣe náà fún ọjọ́ méje sí i.
10 Ní ọjọ́ kẹtàlélógún (23rd day) tí oṣù kéje, ó sì rán àwọn ènìyàn padà sí ilé wọn, pẹ̀lú ayọ̀ àti ìdùnnú nínú wọn fún ohun rere tí Olúwa ti ṣe fún Dáfídì àti Sólómónì, àti fún àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì.
11 Nígbà tí Sólómónì ti parí ilé Olúwa àti ibi ilé ọba, nígbà tí ó sì ti ṣe àṣeyọrí láti gbé jáde gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn láti ṣe nínú ilé Olúwa àti nínú ilé òun tìkálárarẹ̀,
12 Olúwa sì farahàn ní òru ó sì wí pé:“Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti yàn ibííyí fún ara mi gẹ́gẹ́ bí ilé fún ẹbọ.