16 Jéhù wí pé, “Wá pẹ̀lú ù mi; kí o sì rí ìtara mi fún Olúwa.” Nígbà náà ó jẹ́ kí ó gun kẹ̀kẹ́ rẹ̀.
17 Nígbà tí Jéhù wá sí Ṣamáríà, ó pa gbogbo àwọn tí a fi kalẹ̀ ní ìdílé Áhábù; ó pa wọ́n run, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí a sọ sí Èlíjà.
18 Nígbà náà, Jéhù kó gbogbo àwọn ènìyàn jọ, ó sì wí fún wọn pé, “Áhábù sin Báálì díẹ̀; ṣùgbọ́n Jéhù yóò sìn ín púpọ̀.
19 Nísinsìn yìí, ẹ pe gbogbo àwọn wòlíì Báálì jọ, gbogbo àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ àti gbogbo àlùfáà rẹ̀. Rí i wí pé, kò sí nǹkankan tí ó ń sọnù nítorí ẹ̀mi yóò rú ẹbọ ńlá fún Báálì. Ẹnìkíní tí ó bá kọ̀ láti wá, kò ní wà láàyè mọ́.” Ṣùgbọ́n Jéhù fi ẹ̀tàn ṣe é, kí ó lè pa àwọn òjíṣẹ́ Báálì run.
20 Jéhù wí pé, “ẹ pe àpẹ̀jọ ní wòyí ọ̀la fún Báálì.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kéde rẹ.
21 Nígbà náà, ó rán ọ̀rọ̀ káàkiri Ísírẹ́lì, gbogbo àwọn òjíṣẹ́ Báálì sì wá: kò sí ẹnìkan tí ó dúró lẹ́yìn. Wọ́n kún ilé tí a kọ́ fún òrìṣà títí tí ó fi kún láti ìkángun èkíní títí dé èkejì.
22 Jéhù sì sọ fún olùṣọ́ pé, “Kí ó mú aṣọ ìgúnwà wá fún gbogbo àwọn òjíṣẹ́ Báálì.” Bẹ́ẹ̀ ni ó mú aṣọ ìgúnwà jáde wá fún wọn.