2 Ọba 11:7-13 BMY

7 Àti ẹ̀yin tí ó wà ní ẹgbẹ́ kejì yóòkù tí kì í lọ ibi iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi gbogbo ni kí ó ṣọ́ ilé tí a kọ́ fún Olúwa fún ọba.

8 Ẹ mú ibùjókòó yín yí ọba ká, olúkúlùkù ọkùnrin pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ ọgbà yìí gbúdọ̀ kú. Ẹ dúró súnmọ́ ọba ní ibikíbi tí ó bá lọ.”

9 Olórí àwọn ọrọọrún ṣe gẹ́gẹ́ bí Jéhóíádà àlùfáà ti paà láṣẹ́. Olúkúlùkù mú àwọn ọkùnrin rẹ̀ àwọn tí ó ń lọ sí iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi àti àwọn tí wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Jéhóíádà àlùfáà.

10 Nígbà náà, ó fún àwọn olórí ní àwọn ọ̀kọ̀ àti àwọn apata tí ó ti jẹ́ ti ọba Dáfídì tí ó sì wà nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa.

11 Àwọn olùṣọ́, olúkúlùkù pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀, wọ́n sì dúró ṣinṣin yìí ọba ká—lẹ́báá pẹpẹ àti ilé ìhà gúsù sí ìhà àríwá ilé tí a kọ́ fun Olúwa náà.

12 Jéhóíádà mú ọmọkùnrin ọba jáde, ó sì gbé adé náà lé e: ó fún un ní ẹ̀dà májẹ̀mú, wọ́n sì kéde ọba rẹ̀. Wọ́n fi àmì òróró yàn án, àwọn ènìyàn pa àtẹ́wọ́, wọ́n sì kígbe, “Kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn.”

13 Nígbà tí Ataláyà gbọ́ ariwo tí àwọn olùṣọ́ àti àwọn ènìyàn ń pa, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa.