18 Nígbà náà ó wí pé, “Mú àwọn ọfà náà,” ọba sì mú wọn. Èlíṣà wí fún un pé, “Lu ilẹ̀.” Ó lù ú lẹ́ẹ̀mẹ́ta, ó sì dáwọ́ dúró.
19 Ènìyàn Ọlọ́run sì bínú sí i, ó sì wí pé, “Ìwọ kò bá ti lu ilẹ̀ ní ẹẹ̀marùn-ún tàbí ní ẹ̀ẹ̀mẹfà; Nígbà náà, ìwọ kò bá ti ṣẹ́gun Ṣíríà àti pa á run pátapáta ṣùgbọ́n Nísinsìn yìí ìwọ yóò ṣẹ́gun rẹ̀ ní ẹ̀mẹ́ta péré.”
20 Èlíṣà kú a sì sin ín.Ẹgbẹ́ Àwọn ará Móábù máa ń wọ orílẹ̀ èdè ní gbogbo àmọ́dún.
21 Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan ti ń sin òkú ọkùnrin kan, lójijì wọ́n rí ẹgbẹ́ àwọn oníjadì: Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ju òkú ọkùnrin náà sínú ibojì Èlíṣà. Nígbà tí ara ọkùnrin náà kan egungun Èlíṣà, ó padà wá sí ayé, ó sì dúró ní ẹsẹ̀ rẹ̀.
22 Hásáélì ọba Ṣíríà ni Ísírẹ́lì lára ní gbogbo àkókò tí Jéhóáhásì fi jọba.
23 Ṣùgbọ́n Olúwa ṣàánú fún wọn ó sì ní ìyọ́nú, ó sì fiyèsí wọn nítorí májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Ábúráhámù, Ísákì àti Jákọ́bù. Títí di ọjọ́ òní, kì í ṣe ìfẹ́ inú rẹ̀ láti pa wọ́n run tàbí lé wọn lọ níwájú rẹ̀.
24 Hásáélì ọba Ṣíríà kú, Bẹni-Hádádì ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.