1 Ní ọdún kejì tí Jéhóásì ọmọ Jéhóáhásì ọba Ísírẹ́lì, Ámásáyà ọmọ Jóásì ọba Júdà bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba.
2 Ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n. Orúkọ ìyá a rẹ̀ a máa jẹ́ Jéhóádínì; ó wá láti Jérúsálẹ́mù.
3 Ó ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa, ṣùgbọ́n kì í ṣe bí i Dáfídì baba a rẹ̀ tí ṣe. Nínú ohun gbogbo, ó tẹ́lé àpẹrẹ baba a rẹ̀ Jóásì.
4 Àwọn ibi gíga bí ó ti wù kí ó rí, a kò sí i kúrò; Àwọn ènìyàn sì tẹ̀ṣíwájú láti rú ẹbọ àti sun tùràrí níbẹ̀.
5 Lẹ́yìn tí ó ti fi ọwọ́ gbá ìjọba rẹ̀ mú gbọin-gbọin, ó pa àwọn oníṣẹ́ tí wọ́n ti pa baba a rẹ̀ ọba.