2 Ọba 14:10-16 BMY

10 Ìwọ ti ṣẹ́gun Édómù pẹ̀lú, ṣùgbọ́n, nísinsìn yìí ìwọ ṣe ìgbéraga. Ògo nínú ìṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n dúró nílé! Kí ni ó dé tí o fi ń wá wàhálà tí o sì fa ìṣubú rẹ àti ti Júdà pẹ̀lú?”

11 Bí ó ti wù kí ó rí Ámásíà kò ní tẹ́tí, bẹ́ẹ̀ ni Jéhóásì ọba Ísírẹ́lì sì dojúkọ ọ́. Òun àti Ámásáyà ọba Júdà kọjú sí ara wọn ní Bẹti-Ṣéméṣì ní Júdà.

12 A kó ipa ọ̀nà Júdà nípasẹ̀ Ísírẹ́lì, gbogbo àwọn ọkùnrin sì sálọ sí ilé e rẹ̀.

13 Jéhóásì ọba Ísírẹ́lì fi agbára mú Ámásáyà ọba Júdà, ọmọ Jóásì, ọmọ Áhásáyà ní Bẹti-Ṣéméṣì. Nígbà náà, Jéhóásì lọ sí Jérúsálẹ́mù, ó sì lọ wó odi Jérúsálẹ́mù lulẹ̀ láti ìlẹ̀kùn Éfúráímù sí ibi igun ìlẹ̀kùn. Ìpín kan tí ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀ta ẹsẹ̀ bàtà (600).

14 Ó mú gbogbo wúrà àti fàdákà àti gbogbo ohun tí ó rí nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa àti níbi ìfowópamọ́ sí nínú ààfin ọba. Ó mú àwọn ìdógò, ó sì dá wọn padà sí Ṣamáríà.

15 Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Jéhóásì, gbogbo ohun tí ó ṣe pẹ̀lú àṣeyọrí rẹ̀, pẹ̀lú ogun rẹ̀ sí Ámásáyà ọba Júdà, ṣé a kò kọ wọ́n sí inú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì?

16 Jéhóásì sì sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín sí Ṣamáríà pẹ̀lú àwọn ọba Ísírẹ́lì. Jéróbóámù ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.