1 Ní ọdún kẹtàdínlógún Pẹ́kà ọmọ Remálíà, Áhásì ọmọ Jótamù ọba Júdà bẹ̀rẹ̀ síi jọba.
2 Ẹni ogún ọdún ni Áhásì nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ó sì jọba ọdún mẹ́rìndínlógún ní Jérúsálẹ́mù, kò si ṣe èyí tí ó tọ́ lójú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Dáfídì baba rẹ̀.
3 Ṣùgbọ́n ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísíráẹ́lì, nítòótọ́, ó sì mú kí ọmọ rẹ̀ ó kọjá láàrin iná, gẹ́gẹ́ bi iṣẹ́ ìrírà àwọn aláìkọlà, tí Olúwa lé jáde níwájú àwọn ọmọ Ísíráẹ́lì.
4 Ó sì rúbọ, ó sì ṣun tùràrí ní àwọn ibi gíga, àti lórí àwọn òkè kéékèèkéé àti lábẹ́ gbogbo igi tútù.
5 Nígbà náà ni Résínì ọba Ṣíríà àti Pẹ́kà ọmọ Rèmálíà ọba Ísíráẹ́lì gòkè wá sí Jérúsálẹ́mù láti jagun: wọ́n dó ti Áhásì, ṣùgbọ́n wọn kò lè borí rẹ̀.