2 Ọba 17:22-28 BMY

22 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì forítìí nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbámù kò sì yí padà kúrò lọ́dọ̀ wọn

23 Títí tí Olúwa fi mú wọn kúrò níwájú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti paláṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ wòlíì. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì mú wọn kúrò ní ilẹ̀ wọn lọ sí Iṣánṣà ni Ásíríà.

24 Ọba Ásíríà mú àwọn ènìyàn láti Bábílónì, Kútà, Áfà, Hámátì àti Ṣéfáfáímù wọ́n sì dúró ní ìlú Ṣamáríà láti rọ́pò àwọn ará Ísírẹ́lì. Wọ́n sì ń gbé ní ìlú náà.

25 Nígbà tí wọ́n gbé bẹ́ ẹ ní àkọ́kọ́, wọn kò sì bẹ̀rù Olúwa, Bẹ́ẹ̀ ni ó rán kìnnìún sí àárin wọn. Wọ́n sì pa nínú wọn.

26 Wọ́n sì sọ fún ọba Ásíríà pé: “Àwọn ènìyàn tí ìwọ lé kúrò tí o sì fi sínú ìlú Ṣamáríà kò mọ ohun tí Olúwa ìlú náà béèrè. Ó sì ti rán kìnnìún sí àárin wọn, tí ó sì ń pa wọ́n run, nítorí ènìyàn wọn kò mọ ohun tí ó béèrè.”

27 Nígbà náà ọba Ásíríà pàṣẹ yìí wí pé, “Mú ọ̀kan lára àwọn àlùfáà tí ó mú láti Ṣamáríà lọ padà gbé níbẹ̀ kí ó sì kọ́ àwọn ènìyàn ní, ohun tí Olúwa ilẹ̀ náà béèrè.”

28 Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kan lára àwọn àlùfáà tí ó ti kúrò ní Samáríà wá gbé ní Bétélì ó sì kọ́ wọn bí a ti ń sin Olúwa.