22 Omi náà sì ti dára ni mímu títí di òní, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Èlíṣà ti sọ.
23 Láti ibẹ̀ Èlíṣà lọ sókè ní Bétélì gẹ́gẹ́ bí ó ti ń rìn lọ lójú ọ̀nà, àwọn ọ̀dọ́ kan jáde wá láti ìlú náà wọ́n sì fi ṣe ẹlẹ́yà. “Má a lọ sókè ìwọ apárí!” Wọ́n wí pé. “Má a lọ sókè ìwọ apárí!”
24 Ó sì yípadà, ó sì wò wọ́n ó sì fi wọ́n bú ní orúkọ Olúwa. Nígbà náà béárì méjì sì jáde wá láti inú igbó ó sì lu méjìlélógójì (42) lára àwọn ọ̀dọ́ náà.
25 Ó sì lọ sí orí òkè Kámẹ́lì láti ibẹ̀ ó sì padà sí Samáríà.