2 Ọba 23:4-10 BMY

4 Ọba sì pàṣẹ fún Hílíkíáyà olórí àlùfáà àti àwọn, àlùfáà tí ó tẹ̀lée ní ipò àti àwọn olùsọ́nà láti yọ kúrò nínú ilé Olúwa gbogbo ohun èlò tí a ṣe fún Báálì àti Áṣérà àti gbogbo ẹgbẹ́ ogun ọ̀run. Ó sì sun wọ́n ní ìta Jérúsálẹ́mù ní pápá pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kídírónì. Ó sì kó eérú wọn jọ sí Bétélì.

5 Ó sì kúrò pẹ̀lú àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà tí a yàn láti ọwọ́ ọba Júdà láti ṣun tùràrí ní ibi gíga ti ìlú Júdà àti àwọn tí ó yí Jérúsálẹ́mù ká. Àwọn tí ó ń sun tùràrí sí Báálì, sí oòrùn àti òṣùpá, sí àwọn àmì ìràwọ̀ àti sí gbogbo ẹgbẹ́ ogun ọ̀run.

6 Ó mú ère òrìṣà láti ilé Olúwa sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kídírónì ní ìta Jérúsálẹ́mù, ó sì ṣun wọ́n níbẹ̀. Ó lọ̀ ọ́ bí atíkè ó sì fọ́n ekuru náà sórí iṣà òkú àwọn ènìyàn tí ó wọ́pọ̀.

7 Ó sì wó ibùgbé àwọn tí ń ṣe panṣágà lọ́kùnrin o tí ojúbọ wọn lulẹ̀. Tí ó wà nínú ilé Olúwa àti ibi tí àwọn obìnrin tí ń ṣe iṣẹ́ aṣọ híhun fún Áṣérà (òriṣà).

8 Jòṣíáyà kó gbogbo àwọn àlùfáà láti àwọn ìlú Júdà ó sì ba ibi mímọ́ wọ̀n-ọn-nì jẹ́ láti Gébà sí Béríṣébà, níbi tí àwọn àlùfáà ti ṣun tùràrí. Ó wó àwọn ojúbọ lulẹ̀ ní ẹnu ìlẹ̀kùn—ní ẹnu ọ̀nà à bá wọlé ti Jóṣúà, baálẹ̀ ìlú ńlá tí ó wà ní apá òsì ẹnu ìlẹ̀kùn ìlú ńlá.

9 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, àwọn àlùfáà ibi gíga kò jọ́sìn ní ibi pẹpẹ Olúwa ní Jérúsálẹ́mù, wọ́n jẹ nínú àkàrà aláìwú pẹ̀lú àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn.

10 Ó sì ba ohun mímọ́ Tófẹ́tì jẹ́, tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Beni-Hínómì, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnìkan tí ó lè lò ó fún ẹbọ rírú fún ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí ọmọ rẹ̀ obìnrin nínú iná sí Mólékì.