14 Ti kọ́ fún Olúwa, Ó kó wọn lọ sí ìgbékùn gbogbo Jérúsálẹ́mù: gbogbo ìjòyè àti àwọn akọni alágbára ọkùnrin, àti gbogbo oníṣọ̀nà àti ọlọ́nà tí àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ ẹgbàárún ún, àwọn talákà ènìyàn ilẹ̀ náà nìkan ni ó kù.
15 Nebukadinéṣárì mú Jéhóíákínì ní ìgbékùn lọ sí Bábílónì. Ó sì tún mú ìyá ọba láti Jérúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì, ìyàwó rẹ̀ àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn olórí ile náà.
16 Ọba Bábílónì àwọn ọkùnrin ọlọ́lá tí ó jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàarin (7000) alágbára ọkùnrin, alágbára tí ó yẹ fún ogun, àti àwọn ẹgbẹ̀rùn (1000) oníṣọ̀nà àti alágbẹ̀dẹ.
17 Ó sì mú Mátanáyà arákùnrin baba Jéhóíákínì, ọba ní ìlú rẹ̀ ó sì yí orúkọ rẹ̀ padà sí Ṣedekáyà.
18 Ṣedekáyà jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìjọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mọ́kànlá. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hámútalì ọmọbìnrin Jeremáyà; ó sì wá láti Líbínà.
19 Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Jéhóíákínì ti ṣe.
20 Nítorí tí ìbínú Olúwa, ni gbogbo èyí ṣe sẹ sí Jérúsálẹ́mù, àti Júdà, ní òpin ó ta wọ́n nù kúrò níwájú rẹ̀.Nísinsìn yìí Ṣedekíàyà sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Bábílónì.