2 Ọba 25:20-26 BMY

20 Nebukadínésárì olórí àwọn ẹ̀sọ́ kó gbogbo wọn, ó sì mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ ọba Bábílónì ní Ríbílà.

21 Níbẹ̀ ní Ríbílà, ní ilẹ̀ Hámátì, ọba sì kọlù wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni Júdà lọ sí oko ẹrú, kúrò láti ilé rẹ̀.

22 Nebukadínésárì ọba Bábílónì ó mú Gédalíàh ọmọ Áhíkámù ọmọ ṣáfánì, láti jọba lórí àwọn ènìyàn tí ó ti fa kalẹ̀ lẹ́yìn ní Júdà.

23 Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ogun àti àwọn ọkùnrin wọn gbọ́ pé ọba Bábílónì ti yan Gédálíàh gẹ́gẹ́ bí baálẹ̀, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Gédálíàh ni Mísípà. Ísímáélì ọmọ Nétaníàh, Jóhánánì ọmọ Káréà, Séráíáyà ọmọ Tánhúmétì ará Nétófátì, Jásáníáyà ọmọ ara Mákà, àti àwọn ọkùnrin wọn.

24 Gédálíà sì búrà láti fi dá àwọn ènìyàn rẹ̀ lójú. “Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn ìjòyè ará káidéà,” ó wí pé, “Ẹ máa gbé ilẹ̀ náà kí ẹ sì sin ọba Bábílónì, yóò sì dára fún un yín.”

25 Ní oṣù kèje, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé, Ísmáélì ọmọ Nétaníáyà, ọmọ Èlísámà, ẹni tí ó jẹ́ ti ẹ̀jẹ̀ ọba, wá pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mẹ́wàá ó sì kọlù Gédálíáyà àti pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mẹwàá ará Júdà àti àwọn ará káídéà tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Míspà.

26 Nítorí èyí, gbogbo àwọn ènìyàn láti ẹni kékeré títí dé ẹni ńlá, àti pẹ̀lú àwọn olórí ogun, sá lọ si Éjíbítì nítorí ẹ̀rù àwọn ará Bábílónì.