11 Ní ọjọ́ kan nígbà tí Èlíṣà wá, ó lọ sí orí òkè ní yàrá rẹ̀ ó sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀.
12 Ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Géhásì pé, “Pe ará Ṣúnémù.” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì pè é wá, ó sì dúró níwájú rẹ̀.
13 Èlíṣà wí fún un pé, “wí fún un, ‘Ìwọ ti lọ ṣe gbogbo àníyàn iṣẹ́ ìyìnrere fún wa. Nísinsìn yìí kí ni a lè ṣe fún ọ?’ ”“Ṣé alèjẹ́ agbẹnusọ fún ọ ní ọ̀dọ̀ ọba tàbí olórí ogun?”
14 “Kí ni a lè ṣe fún obìnrin yìí?” Èlíṣà béèrè.Géhásì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, kò ní ọmọ, ọkọ rẹ̀ náà sì tún di arúgbó.”
15 Nígbà náà Èlíṣà wí pé, “Pè é,” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì pè é, ó sì dúró ní àbáwọlé ẹnu ọ̀nà.
16 Èlíṣà sọ wí pé, “Ìwòyí ọdún tí ń bọ̀, ìwọ yóò fi ọwọ́ rẹ gbé ọmọ.”“Bẹ́ẹ̀ kọ́, Olúwa mi,” nkò fara mọ́ ọn. “Ma ṣe ṣi ìránṣẹ́ rẹ lọ́nà, ìwọ ènìyàn Ọlọ́run!”
17 Ṣùgbọ́n obìnrin náà lóyún ní ọdún kejì ní àkókò náà, ó bí ọmọ ọkùnrin kan, gẹ́gẹ́ bí Èlíṣà ti sọ fún un.