14 “Kí ni a lè ṣe fún obìnrin yìí?” Èlíṣà béèrè.Géhásì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, kò ní ọmọ, ọkọ rẹ̀ náà sì tún di arúgbó.”
15 Nígbà náà Èlíṣà wí pé, “Pè é,” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì pè é, ó sì dúró ní àbáwọlé ẹnu ọ̀nà.
16 Èlíṣà sọ wí pé, “Ìwòyí ọdún tí ń bọ̀, ìwọ yóò fi ọwọ́ rẹ gbé ọmọ.”“Bẹ́ẹ̀ kọ́, Olúwa mi,” nkò fara mọ́ ọn. “Ma ṣe ṣi ìránṣẹ́ rẹ lọ́nà, ìwọ ènìyàn Ọlọ́run!”
17 Ṣùgbọ́n obìnrin náà lóyún ní ọdún kejì ní àkókò náà, ó bí ọmọ ọkùnrin kan, gẹ́gẹ́ bí Èlíṣà ti sọ fún un.
18 Ọmọ náà dàgbà, ní ọjọ́ kan, ó jáde lọ sí ọ̀dọ̀ bàbá rẹ̀, ó wà pẹ̀lú àwọn olùkórè.
19 “Orí mi!, Orí mi!” Ó wí fún baba rẹ̀.Baba rẹ̀ sọ fún ìránṣẹ́, “Gbé e lọ sọ́dọ̀ ìyá rẹ̀.”
20 Lẹ́yìn ìgbà tí ìránṣẹ́ náà ti gbé e sókè tí ó sì gbé e tọ ìyá rẹ̀ lọ, ọmọ ọkùnrin náà jókòó sórí ẹsẹ̀ rẹ̀ títí ó fi di ọ̀sán gangan, nígbà náà ó sì kú.