7 Ó wí pé, “Gbé e jáde” Nígbà náà ọkùnrin náà na ọwọ́ rẹ̀ jáde ó sì mú un.
8 Nísinsìn yìí ọba Árámù ó wà ní ogun pẹ̀lú Ísírẹ́lì ó sì bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ gbérò, ó wí pé “Èmi yóò ṣe ibùdó mi sí ibí yìí nínú èyí náà àti bí ibí yìí.”
9 Ènìyàn Ọlọ́run rán iṣẹ́ sí ọba Ísírẹ́lì, “kíyèsí ara láti kọjá ní ibẹ̀ yẹn, nítorí pé ará Árámù wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ síbẹ̀.”
10 Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì wo ibi tí ènìyàn Ọlọ́run náà fi hàn, ní ẹ̀ẹ̀kan sí i Èlíṣà kìlọ̀ fún ọba, bẹ́ẹ̀ ni ó wà lórí sísọ ní ibẹ̀.
11 Èyí mú ọba Árámù bínú. Ó pe àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ṣé ìwọ kò ní sọ fún un èwo nínú wa ni ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọba Ísírẹ́lì?”
12 “Kò sí ọ̀kan nínú wa, Olúwa ọba mi,” ọ̀kan lára ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí pé, “ṣùgbọ́n Èlíṣà, wòlíì tí ó wà ní Ísírẹ́lì, sọ fún ọba Ísírẹ́lì ọ̀rọ̀ gangan tí ó sọ nínú yàrá rẹ̀.
13 “Lọ, kí ẹ lọ wo ibi tí ó wà,” ọba pa á láṣẹ, “Kí èmi kí ó lè rán ènìyàn láti lọ mú un wá.” Ìròyìn padà wá. “Ó wà ní Dótanì.”