1 Nísin yìí, Èlíṣà wí fún obìnrin náà tí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin jí pàdà sáyé pé, “jáde lọ pẹ̀lú ìdílé rẹ kí o sì lọ dúró fún ìgbà díẹ̀ ní ibíkíbi tí o bá le dúró sí, nítorí Olúwa ti pàṣẹ ìyàn ní ìlú tí yóò lò tó ọdún méje.”
2 Obìnrin náà tẹ̀ ṣíwájú gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ènìyàn Ọlọ́run ti sọ. Òun àti ìdílé rẹ̀ sá lọ, wọ́n sì dúró ní ilé àwọn ará Fílístínì fún ọdún méje.
3 Ní ẹ̀yìn ọdún méje ó sì padà wá láti ilẹ̀ àwọn ará Fílístínì ó sì lọ sí ọ̀dọ̀ ọba láti lọ bẹ̀ẹ́ fún ilé àti ilẹ̀ rẹ̀.
4 Ọba sì ń sọ̀rọ̀ sí Géhásì, ìránṣẹ́ ènìyàn Ọlọ́run pé, “Sọ fún mi nípa gbogbo ohun ńlá tí Èlísà ti ṣe.”