25 Ní ọdún méjìlá Jórámù ọmọkùnrin Áhábù ọba Ísírẹ́lì, Áhásáyà ọmọkùnrin Jéhórámù ọba Júdà bẹ̀rẹ̀ ìjọba rẹ̀.
26 Áhásáyà jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó di ọba. Ó sì jọba ní ọdún kan ní Jérúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ a sì máa jẹ́ Átalíàh, ọmọbìnrin Ómírìe ọba Ísírẹ́lì.
27 Nígbà tí ó rin ọ̀nà ilé Áhábù ó sì ṣe búburú níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ilé Áhábù ti ṣe, nítorí ó tan nípa ìgbéyàwó sí ìdílé Áhábù.
28 Áhásáyà sì lọ pẹ̀lú Jórámù ọmọ Áhábù lọ sí ogun lórí Hásáélì ọba Árámù ní Ramoti-Gílíádì. Àwọn ará Ṣíríà ṣẹ́ Jórámù lẹ́sẹ̀.
29 Bẹ́ẹ̀ ni ọba Jórámù padà sí Jéṣérẹ́lì láti wo ọgbẹ́ rẹ̀ sàn tí ará Síríà ti jẹ níyà lórí rẹ̀ ní Rámò ní ojú ogun rẹ̀ pẹ̀lú Hásáélì ọba Árámù.Nígbà náà Áhásáyà ọmọ Jéhórámù ọba Júdà sọ̀kalẹ̀ lọ sí Jésérẹ́lì láti lọ wo Jórámù ọmọ Áhábù nítorí tí ó fi ara pa.