34 Jéhù wọ inú ilé lọ, ó jẹ ó sì mu. “Tọ́jú obìnrin yẹn tí a fi bú,” Ó wí, “Kí o sì sin-ín, nítorí ọmọbìnrin ọba ni ó jẹ́.”
35 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n jáde lọ láti lọ sin-ín, wọn kò rí nǹkankan àyàfi agbárí i rẹ̀, ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì àti ọwọ́ ọ rẹ̀ méjèèjì.
36 Wọ́n padà lọ sọ fún Jéhù, ẹni tí ó wí pé, “Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ Èlíjà ará Tíṣíbì wí pé: Ní orí oko Jésérẹ́lì ni àwọn ajá yóò ti jẹ ẹran ara Jésébélì.
37 Òkú Jésébélì yóò dàbí ohun ẹ̀gbin ní orí oko Jésérẹ́lì, débi pé, ẹnikẹ́ni kì yóò lè sọ pé, ‘Jésébélì ni èyí.’ ”