2 Sámúẹ́lì 11:21-27 BMY

21 Ta ni ó pa Ábímélékì ọmọ Jerubu-Bésétì? Kì í ṣe obìnrin ni ó yí òkúta ọlọ lù ú láti orí odi wá, tí ó sì kú ní Tébésì? Èé ha ti rí tí ẹ̀yín fi súnmọ́ odi náà? Ìwọ yóò sì wí fún-un pé, Ùráyà ìránṣẹ́ rẹ ará Hítì kú pẹ̀lú.’ ”

22 Ìránṣẹ́ náà sì lọ, ó sì wá, ó sì jẹ́ gbogbo iṣẹ́ tí Jóábù rán an fún Dáfídì.

23 Ìránṣẹ́ náà sì wí fún Dáfídì pé, “Nítòótọ́ àwọn ọkùnrin náà lágbára jù wá lọ, wọ́n sì jáde tọ̀ wá wá ní pápá, àwa sì tẹ̀lé wọn títí wọ́n fi dé ẹ̀yìn odi.

24 Àwọn tafàtafà sì ta sí ìránṣẹ́ rẹ láti orí odi wá, díẹ̀ nínú àwọn ìránṣẹ́ ọba sì kú, ìránṣẹ́ rẹ̀ Ùráyà ará Hítì sì kú pẹ̀lú.”

25 Dáfídì sì wí fún ìránṣẹ́ náà pé, “Báyìí ni ìwọ yóò wí fún Jóábù pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí nǹkan yìí burú ní ojú rẹ, nítorí pé idà a máa jẹ́ lọ́tún lósì, mú ìjà rẹ le sí ìlú náà, kí o sì bì í ṣubú.’ Kí ìwọ sì mú un lọ́kàn le.”

26 Nígbà tí aya Ùráyà sì gbọ́ pé Ùráyà ọkọ rẹ̀ kú, ó sì ṣọ̀fọ̀ nítorí ọkọ rẹ̀.

27 Nígbà tí ìṣọ̀fọ̀ náà sì kọjá tan, Dáfídì sì ránṣẹ́, o sì mú un wá sí ilé rẹ̀, ó sì di aya rẹ̀, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún un, ṣùgbọ́n nǹkan náà tí Dáfídì ṣe burú níwájú Olúwa.