22 Dáfídì sì wí fún Ítaì pé, “Lọ kí o sì rékọjá!” Ítaì ará Gítì náà sì rékọjá, àti gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn ọmọ kékèké tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀.
23 Gbogbo ìlú náà sì fi ohùn rara sunkún, gbogbo ènìyàn sì rékọjá; ọba sì rékọjá odò Kídírónì, gbogbo àwọn ènìyàn náà sì rékọjá, sí ìhà ọ̀nà ijù.
24 Sì wò ó, Sádókù pẹ̀lú àti gbogbo àwọn ọmọ Léfì tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sí ń ru àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run: wọ́n sì gbé àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run náà sọ̀kalẹ̀; Ábíátarì sí gòkè, títí gbogbo àwọn ènìyàn sì fi dẹ́kun àti máa kọjá láti ìlú wá.
25 Ọba sì wí fún Sádókù pé, “Sì tún gbé àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run náà padà sí ìlú: bí èmi bá rí ojú rere gbà lọ́dọ̀ Olúwa, yóò sì tún mú mi padà wá, yóò sì fi àpótí-ẹ̀rí náà hàn mí àti ibùgbé rẹ̀.
26 Ṣùgbọ́n bí òun bá sì wí pé, ‘Èmi kò ní inú dídùn sí ọ,’ wò ó, èmi nì yìí, jẹ́ kí òun ó ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí o ti tọ́ ní ojú rẹ̀.”
27 Ọba sì wí fún Sádókù àlùfáà pé, “Aríran ha kọ́ ni ọ́? Padà sí ìlú ní àlàáfíà, àti àwọn ọmọ rẹ méjèèjì pẹ̀lú rẹ, Áhímásì ọmọ rẹ, àti Jónátanì ọmọ Ábíátárì.
28 Wò ó, èmi ó dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ijù náà, títí ọ̀rọ̀ ó fi ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá láti sọ fún mi.”