2 Sámúẹ́lì 5:3-9 BMY

3 Gbogbo àgbà Ísírẹ́lì sì tọ ọba wá ní Hébírónì, Dáfídì ọba sì bá wọn ṣe àdéhùn kan ní Hébírónì, níwájú Olúwa: wọ́n sì fi òróró yan Dáfídì ní ọba Ísírẹ́lì.

4 Dáfídì sì jẹ́ ẹni ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó jọba; ó sì jọba ní ogójì ọdún.

5 Ó jọba ní Hébírónì ní ọdún méje àti oṣù mẹ́fà lórí Júdà: ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù ní ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n lórí gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà.

6 Àti ọba àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì lọ sí Jérúsálẹ́mù sọ́dọ̀ àwọn ará Jébúsì, àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà; àwọn tí ó sì ti wí fún Dáfídì pé, “Bí kò ṣe pé ìwọ bá mú àwọn afọ́jú àti àwọn arọ́ kúrò, ìwọ kì yóò wọ ìhín wá” wọ́n sì wí pé, “Dáfídì kì yóò lè wá síhìn ín.”

7 Ṣùgbọ́n Dáfídì fi agbára gba ìlú odì Síónì: èyí náà ni í ṣe ìlú Dáfídì.

8 Dáfídì sọ lọ́jọ́ náà pé, “Ẹnikẹ́ni tí yóò kọlu àwọn ará Jébúsì, jẹ́ kí ó gba ojú àgbàrá, kí o sí kọlu àwọn arọ, àti àwọn afọ́jú tí ọkàn Dáfídì kórìíra.” Nítorí náà ni wọ́n ṣe wí pé, “Afọ́jú àti arọ wà níbẹ̀, kì yóò lè wọlé.”

9 Dáfídì sì jókòó ní ilé àwọn ọmọ ogun tí ó ní odi, a sì ń pè é ní ìlú Dáfídì. Dáfídì mọ ìgànná yí i ká láti Mílò wá, ó sì kọ́ ilé nínú rẹ̀.