1 Díẹ̀ nínú àwọn alàgbà Ísírẹ́lì wá sọ́dọ̀ mi, wọ́n sì jókòó níwájú mi,
2 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
3 “Ọmọ ènìyàn, àwọn ọkùnrin wọnyìí ti gbé òrìṣà kalẹ̀ sínú ọkàn wọn, wọ́n sì gbé àwọn ohun tó lè mú wọn ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ síwájú wọn. Ṣé ó tún yẹ kí n gbà wọ́n láàyè láti wádìí lọ́dọ̀ mi rárá bi? Nítorí náà, sọ fún wọn pé:
4 ‘Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Bí ẹnikẹ́ni ní ilé Ísírẹ́lì tó ó gbé òrìṣà sí ọkàn wọn, tó tún gbé ohun ìkọ̀sẹ̀ ṣíwájú rẹ̀, bá wá sọ́dọ̀ wòlíì, Èmi Olúwa fúnra mi ni n ó dá a lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà ìbọ̀rìṣà rẹ.
5 N ó ṣe èyí láti gba ọkàn àwọn ará Ísírẹ́lì tó ti tẹ̀lé òrìṣà wọn lọ padà sí ọ̀dọ̀ mi.’