1 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
2 “Ọmọ ènìyàn, ò ń gbé láàrin ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn. Wọ́n lójú láti fi ríran, ṣùgbọ́n wọn kò ríran, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n létí láti fi gbọ́ran ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ran, torí pé ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn ni wọ́n.
3 “Nítorí náà, Ọmọ ènìyàn, palẹ̀ ẹrù rẹ mọ́ láti lọ sí ìgbèkùn, lọ́san gangan lójú wọn, kúrò láti ibi tí o wà lọ sí ibòmíràn. Bóyá bí wọ́n bá rí ọ, yóò yé wọn, wọn ó sì ronú bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.
4 Di ẹrù ìgbèkùn rẹ lójú wọn lọ́sàn án gangan, nígbà tó bá sì di alẹ́, loju wọn máa lọ sí ìgbèkùn gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ó lọ ìgbèkùn ṣe máa ń ṣe.
5 Dá ògiri lu lójú wọn, kí o sì gba ibẹ̀ kó ẹrù rẹ jáde.
6 Gbé ẹrù rẹ lé èjìká lójú wọn, bo ojú rẹ, kí o má ba à rí ilẹ̀, sì ru ẹrù rẹ lọ lálẹ́ nítorí pé mo fi ọ́ ṣe àmì fún ilé Ísírẹ́lì.”
7 Mo ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún mi. Mo kẹ́rù mi jáde lọ́sàn án láti lọ fun ìgbèkùn. Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, mo dá ògiri lu pẹ̀lú ọwọ́ mi. Mo sì gbẹ́rù mi léjìká nínú òkùnkùn lójú wọn.
8 Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
9 “Ọmọ ènìyàn, Ǹjẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ilé Ísírẹ́lì tilẹ̀ bi ọ́ pé, ‘Kí lohun tó ń ṣe túmọ̀ sí?’
10 “Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ yìí kan àwọn ọmọ aládé Jérúsálẹ́mù àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì tó wà láàrin rẹ.
11 Sọ fún wọn, Mo jẹ́ àmì fún yín’.“Gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe, bẹ́ẹ̀ la ó ṣe sí wọn. Wọn ó kó lọ sí ìgbèkùn. Gẹ́gẹ́ bí ẹni ti a dè ní ìgbèkùn
12 “Ọmọ aládé tó wà láàrin wọn yóò di ẹrù rẹ lé èjìká lálẹ́ yóò sì jáde lọ, òun náà yóò da ògiri lu kí ó le gba ibẹ̀ jáde. Yóò sì bo ojú rẹ̀ kí ó má ba à rí ilẹ̀.
13 N ó ta àwọ̀n mi lé e lórí, yóò sì kó sínú okùn, N ó sì mú lọ sí Bábílónì, ní ilẹ̀ Kádíyà, ṣùgbọ́n kò ní fojú rí ilẹ̀ náà ibẹ̀ ni yóò kú sí.
14 Gbogbo àwọn tó yí i ká láti ràn án lọ́wọ́ (opá ìtẹ̀lẹ̀ àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀) ni N ó túká sí afẹ́fẹ́, n ó sì tún fi idà lé wọn kiri.
15 “Wọn ó sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, tí mo bá tú wọn ká láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, tí mo sì fọ́n wọn ká sí ilẹ̀ káàkiri.
16 Ṣùgbọ́n n ó ṣẹ́ díẹ̀ kù lára wọn, lọ́wọ́ idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn, kí wọn le jẹ́wọ́ gbogbo ìṣe ìríra wọn láàrin àwọn orílẹ̀ èdè yìí. Nígbà náà ni wọn ó mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.”
17 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
18 “Ọmọ ènìyàn, jẹ oúnjẹ rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀gbọ̀n rìrì, sì mu omi rẹ pẹ̀lú ìwárìrì àti àìbalẹ̀ àyà.
19 Sọ fún àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà pé, ‘Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí; fún àwọn olùgbé Jérúsálẹ́mù àti ilẹ̀ Ísírẹ́lì pé: Pẹ̀lú àìbalẹ̀ àyà ni wọn ó máa jẹun wọn, wọn ó sì mu omi pẹ̀lú àìnírètí, kí ilẹ̀ wọn lè di ahoro torí ìwà ipá àwọn tó ń gbé ibẹ̀.
20 Ìlú tó jẹ́ ibùgbé ènìyàn tẹ́lẹ̀ yóò di òfo, ilẹ̀ náà yóò sì di ahoro. Ẹ ó sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’ ”
21 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé:
22 “Ọmọ ènìyàn, irú òwé wo lẹ ń pa nílẹ̀ Ísírẹ́lì pé: ‘A fa ọjọ́ gùn, gbogbo ìran di asán’?
23 Sọ fún wọn, ‘Èmi yóò fi òpin sí òwe yìí, wọn kò ní ipa mọ́ ní Ísírẹ́lì.’ Sọ fún wọn, ‘Ọjọ́ náà súnmọ́ tòsí nígbà tí gbogbo ìran àti ìsọtẹ́lẹ̀ yóò sì wá sí ìmúṣẹ́.
24 Nítorí kò ní sí ìran asán tàbí àfọ̀ṣẹ yẹ̀yẹ́ mọ́ láàrin ilé Ísírẹ́lì.
25 Ṣùgbọ́n Èmi Olúwa yóò sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ tí mo sọ yóò sì ṣẹ láì falẹ̀. Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí, ní àsìkò yín, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀ ilé ni Èmi yóò mú ọ̀rọ̀ yówù tí mo bá sọ ṣẹ.’ ”
26 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé:
27 “Ọmọ ènìyàn, ilé Ísírẹ́lì ń wí pé, ‘Ìran ọjọ́ pípẹ́ ni ó rí, ó sì sọtẹ́lẹ̀ nípa àsìkò tó jìnnà réré.’
28 “Nítorí náà sọ fún wọn, ‘Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Kò sí ọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ mi tí yóò sún ṣíwájú mọ́; ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí mo bá sọ yóò ṣẹ.’ ”