1 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
2 “Ọmọ ènìyàn, obìnrin méjì wà, ọmọ ìyá kan náà.
3 Wọn ń ṣe panṣágà ní Éjíbítì, wọn ń ṣe panṣaga láti ìgbà èwe wọn. Ní ilẹ̀ yẹn ni wọn ti fi ọwọ́ pa ọyàn wọn, níbẹ̀ ni wọn sì fọwọ́ pa igbá àyà èwe wọn.
4 Èyí ẹ̀gbọ́n ń jẹ́ Óhólà, àbúrò rẹ̀ sì ń jẹ́ Óhólíbà. Tèmí ni wọn, wọ́n sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. Óhólà ni Samaríà, Óhólíbà sì ni Jérúsálẹ́mù.
5 “Óhólà ń ṣe asẹ́wó nígbà tí ó sì jẹ́ tèmi; Ó sì ṣe ìfẹ́kúfẹ́ sí àwọn olólùfẹ̀ rẹ̀, àwọn jagunjagun ará Ásíríà.
6 Aṣọ aláró ni a fi wọ̀ wọ́n, àwọn gómìnà àti àwọn balógun, gbogbo wọn jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin arẹwà àwọn tí ń gun ẹsin.
7 O fi ara rẹ̀ fún gbajúmọ̀ ọkùnrin Ásíríà gẹ́gẹ́ bí pansága obìnrin, o fi òrìsà gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí i sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́,
8 kò fi ìwa aṣẹ́wó tí ó ti bẹ̀rẹ̀, ni Éjíbítì sílẹ̀, ní ìgbà èwe rẹ̀ àwọn ọkùnrin n bá a sùn, wọn fi ọwọ́ pa àyà èwe rẹ̀ lára wọn sì ń ṣe ìfẹ́kúùfẹ́ sí i.
9 “Nítorí náà mo fi i sílẹ̀ fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, ará Ásíríà, tí ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí i.
10 Wọ́n bọ́ ọ sí ìhòòhò, wọ́n sì gba àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ̀ wọn sì pá wọn pẹ̀lú idà. Ó di ẹni ìfisọ̀rọ̀ sọ láàrin àwọn obìnrin wọ́n sì fi ìyà jẹ ẹ́.
11 “Àbúrò rẹ̀ Óhólíbà rí èyí, síbẹ̀ nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti aṣẹ́wó rẹ̀, Ó ba ara rẹ jẹ́ ju ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ.
12 Oun náà ní ìfẹ́kúùfẹ́ sí ará Ásíríà àwọn gómìnà àti àwọn balógun, jagunjagun nínú aṣọ ogun, àwọn tí ń gun ẹṣin, gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin arẹwà.
13 Mo rí i pé òun náà ba ara rẹ̀ jẹ́; àwọn méjèèjì rìn ojú ọ̀nà kan náà.
14 “Ṣùgbọ́n ó tẹ̀ ṣíwájú nínú ṣíṣe aṣẹ́wó. O ri àwòrán àwọn ọkùnrin lára ògiri, àwòrán àwọn ara Kálídíà àwòrán púpa,
15 pẹ̀lú ìgbànú ni ìdí wọn àti àwọn ìgbàrí ni orí wọn; gbogbo wọn dàbí olórí kẹ̀kẹ́ ogun Bábílónì ọmọ ìlú Kálídíà.
16 Ní kété tí ó rí wọn, ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí wọn, ó sì rán onísẹ́ sí wọn ni Kálídíà.
17 Àwọn ará Bábílónì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, lórí ìbùsùn ìfẹ́, nínú ìfẹ́kúùfẹ́ wọn, wọ́n bà á jẹ́. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n bà á jẹ́ tán, ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn ní ìtìjú.
18 Nígbà tí ó tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ aṣẹ́wó rẹ̀ ní gbangba wọ́n sì túu sí ìhòòhò, mo yí padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ ní ìtìjú, gẹ́gẹ́ bí mo ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀.
19 Síbẹ̀síbẹ̀ ó ń pọ̀ síi nínú ìdàpọ̀ rẹ̀ bí ó ti ń rántí ìgbà èwe rẹ̀ tí ó jẹ́ asẹ́wó ní Éjíbítì.
20 Níbẹ̀ ni ó ti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, tí àwọn tí ǹnkan ọkùnrin wọn dàbí ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn ẹni tí ìtíjáde ara wọn dàbí ti àwọn ẹṣin.
21 Ó ń fojúsọ́nà sí àìlófin ìgbà èwe rẹ̀ ni Éjíbítì, nìgbà tí wọ́n fi ọwọ́ pa igbáàyà rẹ̀ àti ọmú ìgbà èwe rẹ̀.
22 “Nítorí náà, Óhólíbà, báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò gbé olólùfẹ́ rẹ dìde sí ọ, àwọn tí o kẹ́yìn si ní ìtìjú, èmi yóò sì mú wọn dojú kọ ọ́ ní gbogbo ọ̀nà
23 àwọn ará Bábílónì àti gbogbo ara Kálídíà àwọn ọkùnrin Pékódùk àti Ṣóà àti Kóà àti gbogbo ará Ásíríà pẹ̀lú wọn, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin arẹwà, gbogbo àwọn gómìnà àti balógun, olórí oníkẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn onípò gíga, gbogbo àwọn tí ń gun ẹṣin.
24 Wọn yóò wa dojú kọ ọ pẹ̀lú ohun ìjà, kẹ̀kẹ́ ogun pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ẹrù àti pẹ̀lú ìwọ́jọpọ̀ ènìyàn; wọn yóò mú ìdúró wọn lòdì sí ọ ní gbogbo ọ̀nà pẹ̀lú àṣà ńlá àti kékeré pẹ̀lú àsíborí. Èmi yóò yí ọ padà sí wọn fun ìjìyà, wọn yóò sì fi ìyà jẹ ọ gẹ́gẹ́ bí wọn tí tó.
25 Èmi yóò sì dojú ìbínú owú mi kọ ọ́, wọn yóò sì fìyà jẹ ọ́ ní ìrunnú. Wọ́n yóò gé àwọn imú àti àwọn ètí yín kúrò, àwọn tí ó kù nínú yín yóò ti ipá idà ṣubú. Wọn yóò mú àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọkùnrin yín lọ, àwọn tí o kù nínú yín ni iná yóò jó run.
26 Wọn yóò sì kó àwọn aṣọ àti àwọn ohun ọ̀ṣọ́ iyebíye yín.
27 Èmi yóò sì fi òpin sí ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti iṣẹ́ aṣẹ́wó tí ẹ bẹ̀rẹ̀ ni Éjíbítì. Ẹ̀yin kò ní wo àwọn nǹkan wọ̀nyí pẹ̀lú aáyun, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní rántí Éjíbítì mọ.
28 “Nítorí báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò fi ọ lé ọwọ́ àwọn tí ó korìíra, lọ́wọ́ àwọn ẹni tí ọkàn rẹ ti sí kúrò.
29 Wọn yóò fìyà jẹ ọ́ pẹ̀lú ìkórìíra, wọn yóò sì kó gbogbo ohun tí o ṣiṣẹ́ fún lọ. Wọn yóò fi ọ́ sílẹ̀ ní ìhòòhò goloto, ìtìjú iṣẹ́ aṣẹ́wó rẹ ni yóò farahàn. Ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti ìdàrúdàpọ̀ rẹ
30 ni ó mú èyí wá sórí rẹ, nítorí tí ìwọ ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ si orílẹ̀ èdè, o sì fi àwọn òrìṣà rẹ́ ara rẹ jẹ.
31 Ìwọ ti rin ọ̀nà ti ẹ̀gbọ́n rẹ rìn; Èmi yóò sì fi aago rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́.
32 “Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè:“Ìwọ yóò mu nínú aago ẹ̀gbọ́n rẹ,aago tí ó tóbi tí ó sì jinnú:yóò mú ìfisẹ̀sín àti ìfiṣe ẹlẹ́yà wá,nítorí tí aago náà gba nǹkan púpọ̀.
33 Ìwọ yóò mu àmupara àti ìbànújẹ́,aago ìparun àti ìsọdahoroaago ẹ̀gbọ́n rẹ Samaríà.
34 Ìwọ yóò mú un, ni àmugbẹ;ìwọ yóò sì fọ sí wẹ́wẹ́ìwọ yóò sì fa ọmú rẹ̀ ya.Èmi ti sọ̀rọ̀ ni Olúwa Olódùmarè wí.
35 “Nítorí náà báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Níwọ̀n bí ìwọ ti gbàgbé mi, tí iwọ sì ti fi mi sí ẹ̀yìn rẹ, ìwọ gbọdọ̀ gba àbájáde ìfẹ́kúfẹ́ àti aṣẹ́wó rẹ.”
36 Olúwa sọ fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, ń jẹ́ ìwọ yóò ṣe ìdájọ́ Óhólà àti Óhólíbà? Nítorí náà dojú kọ wọn nípa ìkórìíra tí wọn ń ṣe,
37 nítorí wọn ti dá ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà ẹ̀jẹ̀ sì wà ní ọwọ́ wọn. Wọn dá ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà pẹ̀lú àwọn orìṣà wọn; kódà wọ́n fi àwọn ọmọ wọn tí wọn bí fúnni ṣe ìrúbọ, gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ fún wọn.
38 Bákan náà ni wọ́n ti ṣe èyí náà sí mi: Ní àkókò kan náà wọn ba ibi mímọ́ mi jẹ́, wọ́n sì lo ọjọ́ ìsinmi mi ní àìmọ́.
39 Ní ọjọ́ náà gan an wọ́n fi àwọn ọmọ wọn rúbọ sí àwọn òrìṣà, wọn wọ ibi mímọ́ mi lọ wọn sì lò ó ní ìlòkúlò. Ìyẹn ní wọn ṣe ní ilé mi.
40 “Wọn tilẹ̀ rán oníṣẹ́ sí àwọn ènìyàn tí wọ́n wá láti ọ̀nà jíjìn, nígbà tí wọ́n dé, ìwọ wẹ ara rẹ fún wọn, ìwọ kún ojú rẹ, ìwọ sì fi ọ̀sọ́ iyebíye sára,
41 Ìwọ jókòó lórí ibùsùn ti o lẹ́wà, pẹ̀lú tábìlì tí a tẹ́ ní iwájú rẹ lórí, èyí tí o gbé tùràrí àti òróró tí ó jẹ́ tèmi kà.
42 “Ariwo ìjọ ènìyàn tí kò bìkítà wà ní àyíká rẹ̀; a mú Sábéánì láti ihà pẹ̀lú àwọn ọkùnrin láti ara àwọn ọ̀pọ̀ èniyàn aláìníláárí, wọ́n sì mú àwọn ẹ̀gbà ọrùn ọwọ́ sí àwọn ọwọ́ obìnrin náà àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀, adé dárádárá sì wà ní orí wọn.
43 Lẹ́yìn náà mo sọ̀rọ̀ nípa èyí tí ó lo ara rẹ̀ ṣá nípa aṣẹ́wó ṣíṣe, ‘Nísìnyí jẹ kí wọn lo o bí aṣẹ́wó, nítorí gbogbo ohun tí ó jẹ́ nìyẹn.’
44 Wọn ba sùn bí ọkùnrin ti bá aṣẹ́wó sùn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe sùn pẹ̀lú obìnrin onífẹ̀kúfẹ̀ẹ́, Óhólà àti Óhólíbà.
45 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin olódodo yóò pàṣẹ pé kí wọ́n fi ìyà jẹ àwọn obìnrin tí ó dá ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè tí ó sì ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ nítorí pé aṣẹ́wó ni wọ́n ẹ̀jẹ̀ sì wà ní ọwọ́ wọn.
46 “Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Mú àgbájọ àwọn ènìyàn kénìyàn wá sọ́dọ̀ wọn ki ó sì fi wọn lé ọwọ́ ìpayà àti ìkógun.
47 Àwọn ènìyànkénìyàn náà yóò sọ wọ́n ni òkúta, yóò sì gé wọn lulẹ̀ pẹ̀lú idà wọn; wọn ó sì pa àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn, wọ́n ó sì jó àwọn ilé wọn kanlẹ̀.
48 “Èmi yóò sì fi òpin sí ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ni ilẹ̀ náà, kí gbogbo àwọn obìnrin le gba ìkìlọ̀ kí wọn kí ó ma sì ṣe fara wé ọ.
49 Ìwọ yóò sì jìyà fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ, ìwọ yóò sì gba àbájáde àwọn ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà tí o dá. Nígbà náà ìwọ yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Olódùmarè.”