1 “Kọ orin ọ̀fọ̀ nítorí àwọn ọmọ aládé Ísírẹ́lì
2 wí pé:“ ‘Èwo nínú abo kìnnìnu ni ìyá rẹ̀ ní àárin àwọn kìnnìún yóòkù?Ó sùn ní àárin àwọn ọ̀dọ́ kìnnìún ó sì ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀.
3 Ó sì tọ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà, ó sì di kìnnìún tó ní agbára,ó kọ́ ọ láti sọdẹ, ó sì ń pa àwọn ènìyàn jẹ.
4 Àwọn orílẹ̀ èdè gbọ́ nípa rẹ̀,wọ́n sì fi ẹ̀wọ̀n mú un nínú ààfin wọn.Wọn fi ẹ̀wọ̀n mu nu lọ sí ilẹ̀ Éjíbítì.
5 “ ‘Nígbà tí abo kìnìún yìí rí pé ìrètí rẹ̀ sì já sí asán,ó mú ọmọ rẹ̀ mìíràn ó sì tún tọ́ ọ dàgbà di kìnnìún tó ní agbára.
6 Ó sì ń rìn káàkiri láàrin àwọn kìnnìún nítorí pé ó ti lágbára,o kọ ọdẹ ṣíṣe, ó sì pa àwọn ènìyàn.
7 Ó sì wó odi wọn palẹ̀ ó sì sọ àwọ̀n ìlú wọn di ahoro.Ilẹ̀ náà àti àwọn olùgbé ibẹ̀ sì wà ní ìpayà nítorí bíbú ramúramù rẹ̀.
8 Nígbà náà ni àwọn orílẹ̀ èdè tó yìí ká dìde sí i,wọn ta ẹ̀wọ̀n fún un, wọn sì mú nínú ihò wọn.
9 Wọn fi ìkọ́ gbé e sínú ago, wọn mú un lọ sí ọ̀dọ̀ Ọba Bábílónì,wọn fi sínú ìhámọ́, a kò sì gbọ́ bíbú rẹ̀ mọ́ lórí òkè Ísírẹ́lì.
10 “ ‘Ìyá rẹ dàbí àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ̀;tí á gbìn sí etí odò ó, kún fún èso,ó sì kún fún ẹ̀ka nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi,
11 Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ lágbára tó láti fi ṣe ọ̀pá àṣẹ ìjòyè,ó ga sókè láàrin ewé rẹ̀,gíga rẹ̀ hàn jáde láàrin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ka rẹ̀.
12 Ṣùgbọ́n a hú àjàrà yìí pẹ̀lú ìbínú,á sì wo o lulẹ̀, afẹ́fẹ́ láti ìlà oorùn sì mú koko,wọ́n sọ ọ́ di aláìléso,àwọn ẹka rẹ̀ tó lágbára tẹ́lẹ̀ sì rọ wọ́n sì jó wọn.
13 Báyìí, a tún ún gbìn sínú aṣálẹ̀ ni ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tó ń pọ̀ǹgbẹ omi.
14 Iná sì jáde láti ọ̀kan lára ẹ̀ka rẹ̀ ó sì pa ẹ̀ka àti èso rẹ̀ run,débi pé kò sí ẹ̀ka tó lágbára lórí rẹ̀ mọ́; èyí to ṣe e fi ṣe ọ̀pá fún olórí mọ́.’Èyí ni orin ọ̀fọ̀ a o sì máa lo bí orin ọ̀fọ̀.”