Ísíkẹ́lì 2 BMY

Ọlọ́run Pe Ísíkẹ́lì

1 Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, dìde dúró lórí ẹṣẹ̀ rẹ. Èmi yóò bá ọ sọ̀rọ̀.”

2 Bí ó ṣe ń sọ̀rọ̀, ẹ̀mí sì wọ inú mi ó mú mi dúró lórí ẹsẹ̀ mi, mo sì ń gbọ́ tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀.

3 Ó sọ pé, “Ọmọ ènìyàn, mo ń rán ọ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, sí ọlọ̀tẹ̀ orílẹ̀ èdè tí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi; àwọn àti baba ńlá wọn ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi títí di òní-olónìí.

4 Àwọn ènìyàn tí mo ń rán ọ sí jẹ́ aláìgbọ́ràn àti ọlọ́kàn líle. Sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí’

5 Bí wọn fẹ́tísílẹ̀ tàbí wọn kò fẹ́tísílẹ̀—nítorí pé ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n—wọn yóò mọ̀ pé wòlíì kan wà láàrin wọn.

6 Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn, má ṣe bẹ̀rù wọn tàbí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn. Má ṣe bẹ̀rù, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òṣùṣú àti ẹ̀gún yí ọ ká, tí o sì ń gbé àárin àwọn àkéekèé. Má ṣe bẹ̀rù ohun tí wọ́n ń sọ tàbí bẹ̀rù wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ìdílé ni wọ́n.

7 Ìwọ gbọdọ̀ sọ ọ̀rọ̀ mi fún wọn, bí wọ́n gbọ́ bí wọn kọ̀ láti gbọ́ torí pé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.

8 Ṣùgbọ́n ìwọ, ọmọ ènìyàn, gbọ́ ohun tí mo ń sọ fún ọ. Má se ṣọ̀tẹ̀ bí i ti ìdílé ọlọ́tẹ̀; la ẹnu rẹ kí o sì jẹ ohun tí mo fún ọ.”

9 Mo sì wò, mo sì rí ọwọ́ kan tí a nà sí mi. Ìwé tí a ká sì wà níbẹ̀,

10 ó sì tú ìwé náà fún mi. Ní ojú àti ẹ̀yìn ìwé náà ni a kọ ohùnréré ẹkún, ọ̀fọ̀ àti ègún sí.