Ísíkẹ́lì 16 BMY

Òwe Nípa Àìṣododo Jérúsálẹ́mù

1 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:

2 “Ọmọ ènìyàn, mú kí Jérúsálẹ́mù mọ gbogbo ìwà ìríra rẹ̀.

3 Sọ pé, ‘Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí sí Jérúsálẹ́mù: Ìran rẹ àti ilẹ̀ ìbí rẹ wà ní ilẹ̀ Kénáànì; ará Ámórì ni baba rẹ̀, ìyá rẹ̀ sì jẹ́ ará Hítì.

4 Ní ọjọ́ tí a bí ọ, a kò gé okùn ìwọ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì fomi wẹ̀ ọ́ láti mú kí o mọ́, tàbí ká fiyọ̀ pa ọ́ lára tàbí ká fi aṣọ wé ọ.

5 Kò sẹ́ni tó ṣàánú tàbí kẹ́dùn rẹ débi àtiṣe ikankan nínú iwọ́nyi fún ọ ṣùgbọ́n lọ́jọ́ ìbí rẹ, ìta la jù ọ́ sí torí wọ́n kórìíra rẹ.

6 “ ‘Nígbà tí mo sì kọjá tí mo rí ọ tó ń jàgùdù nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ, mo sọ fún ọ pé, “Yè!”

7 Mo mú ọ dàgbà bí ohun ọ̀gbìn inú oko. O ga sókè, o sì dàgbà, o wá di arẹwà jùlọ, ọmú rẹ yọ, irun rẹ gùn, ìwọ tí o wà ní ìhòòhò láì fi nǹkan kan bora.

8 “ ‘Nígbà tí mo tún kọjá, tí mo rí ọ, mo rí i pé àsìkò àti nífẹ́ rẹ ti tó, mo fi iṣẹtí aṣọ mi bo ìhòòhò rẹ. Mo jẹ́jẹ̀ẹ́ fún ọ mo sì bá ọ dá májẹ̀mú láti di tèmi, ni Olúwa Ọlọ́run wí,

9 “ ‘Nígbà náà ni mo fi omi wẹ ẹ̀jẹ̀ kúrò lára rẹ, mo fi ìpara pa ọ́ lára.

10 Mo fi aṣọ oníṣẹ́ ọ̀nà sí ọ lára láti wọ̀ ọ́, mo wọ bàtà aláwọ fún ọ. Mo fi aṣọ funfun lẹlẹ àti aṣọ olówó iyebíye ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́.

11 Mo fi ohun ọ̀ṣọ́ ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́, mo fi ẹ̀gbà ọwọ́ sí ọ lọ́wọ́, mo fi ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn sí ọ lọ́rùn,

12 Mo sì tún fi òrùka sí ọ nímú, mo fi yẹtí sí ọ létí, mo sì fi adé tó rẹwà dé ọ lórí.

13 Báyìí ni mo ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú wúrà àti fàdákà; tí aṣọ rẹ jẹ́ funfun lẹlẹ, olówó iyebíye àti aṣọ tí a ṣiṣẹ́ ọnà sí. Ìyẹ̀fun kíkúnná, oyin àti òróró ni oúnjẹ rẹ. O di arẹwà títí o fi dé ipò ayaba.

14 Òkìkí rẹ sì kàn káàkiri orílẹ̀ èdè nítorí ẹwà rẹ, nítorí dídán tí mo fi ṣe ẹwà rẹ láṣe pé, ni Olúwa Ọlọ́run wí.

15 “ ‘Ṣùgbọ́n, o gbẹ́kẹ̀lé ẹwà rẹ, o sì di alágbérè nítorí òkìkí rẹ. O sì fọ́n oju rere rẹ káàkiri sórí ẹni yòówù tó ń kọjá lọ, ẹwà rẹ sì di tìrẹ.

16 O mú lára àwọn aṣọ rẹ, láti rán aṣọ aláràbarà fún ibi giga òrìṣà tí o ti ń ṣàgbèrè. Èyí kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀, tàbí kó tilẹ̀ ṣẹlẹ̀ rárá.

17 O tún mú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ dáradára tí mo fi wúrà àti fàdákà ṣe fún ọ láti fi yá ère ọkùnrin tí ó ń bá ọ ṣe àgbèrè papọ̀.

18 O sì wọ ẹ̀wù oníṣẹ́ ọnà rẹ fún wọn, o sì tún gbé òróró àti tùràrí mi sílẹ̀ níwájú wọn.

19 O tún gbé oúnjẹ tí mo fún ọ-ìyẹ̀fún dáradára, òróró àti oyin-fún wọn gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun olóòórùn dídùn; ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyìí, ni Olúwa Ọlọ́run wí.

20 “ ‘Àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin tí o bí fún mi lo ti fi rúbọ bí oúnjẹ fún àwọn òrìṣà. Ṣé ìwà àgbèrè rẹ kò ha tó bí?

21 Ẹ dú àwọn ọmọ mí lọ́rùn, o fà wọ́n fún ère gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun,

22 Nínú gbogbo iṣẹ́ ìríra àti ìwà àgbérè rẹ, o kò rántí ìgbà èwe rẹ, nígbà tó o wà ní ìhòòhò, tó ń jàgùdù nínú ẹ̀jẹ̀.

23 “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí, ‘Ègbé! Ègbé ni fún ọ. Lẹ́yìn gbogbo ìwà búburú rẹ,

24 O kọ́lé amọ̀ fún ara rẹ, o sì kọ́ ojúbọ gíga sí gbogbo òpin oju pópó.

25 Ní gbogbo òpin ojú pópó lo kọ ojúbọ gíga sí tó o sì fi ẹwà rẹ̀ wọlé, o sọ àgbèrè rẹ di púpọ̀ nípa fífi ara rẹ sílẹ̀ fún gbogbo ẹni tó ń kọjá lọ.

26 O ṣe àgbèrè pẹ̀lú ará Éjíbítì tí í ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ aládúgbò rẹ láti mú mi bínú pẹ̀lú ìwà àgbèrè rẹ tó ń pọ̀ sí i.

27 Nítorí náà ni mo fi na ọwọ mi lòdì sí ọ, mo ge ilé rẹ kúrú; èmi yóò sì mú ìfẹ́ àwọn to korìíra rẹ ṣẹ́ lé ọ lórí, àwọn ọmọbìnrin Fílístínì ti ìwàkiwà rẹ̀ jẹ ìyàlẹ́nu fún,

28 Nítorí àìnítẹ́lọ́rùn rẹ o ṣàgbérè pẹ̀lú ara Ásíríà; síbẹ̀ náà, o kò tún ní ìtẹ́lọ́rùn.

29 Ìwà àgbèrè rẹ tún tẹ̀ṣíwájú dé ilẹ̀ oniṣòwò ni Bábílónì síbẹ̀ náà, o kò tún ni ìtẹ́lọ́rùn.

30 “Olúwa Ọlọ́run wí pé, ‘Báwo ni ọkàn rẹ ṣe jẹ aláìlera tó tí o n ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ àwọn agídí alágbérè!

31 Nígbà tí o kọ́lé funra rẹ, tóo sì tún kọ ojúbọ gíga si gbogbo òpin ojú pópó síbẹ̀, o ko tún ṣe bi àwọn alágbèrè gidi nítorí pé o kọ̀ láti gbowó

32 “ ‘Ìwọ alágbèrè aya! Ìwọ fẹ́ràn ọkùnrin àjèjì ju ọkọ rẹ lọ!

33 Àwọn ọkùnrin máa ń sanwó fún àwọn aṣẹwó ni ṣùgbọ́n ìwọ lo tún ń sanwó fun wọn, tí ó tún ń fún àwọn olólùfẹ́ rẹ lẹ́bùn àti owó ẹ̀yìn kí wọn bá à le máa wá ọ wá láti gbogbo agbègbè fún àgbèrè ṣíṣe.

34 Nínú àgbèrè rẹ ìwọ yàtọ̀ sí àwọn alágbèrè obìnrin yòókù; kò sí ẹni tó ń wá ọ fún àgbèrè. Ìwọ ló ń sánwó: nígbà tí wọn yóò sanwó fún ọ, ìdákejì ni ọ́; nítorí pé ìwọ ló ń sanwo bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò rí gbà.

35 “ ‘Nítorí náà, ìwọ alágbèrè, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa!

36 Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Nítorí pé ìwọ tú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ jáde, ìwọ sì fi ìhòòhò rẹ hàn, nípa ṣíṣe àgbèrè pẹ̀lú àwọn olólùfẹ̀ẹ̀ rẹ, àti nítorí gbogbo ère tí o fi ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ rẹ ṣe ìrúbọ fún,

37 nítorí náà, Èmi yóò ṣa gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ jọ, pẹ̀lú gbogbo àwọn ti ẹ jọ ṣe fàájì, àwọn tí ìwọ fẹ́ àti àwọn tí ìwọ korìíra. Èmi yóò ṣa gbogbo wọn káàkiri, láti mú wọn lòdì sí ọ, èmi yóò sí aṣọ rẹ, níwájú wọn, wọn yóò sì rí ìhòòhò rẹ.

38 Èmi yóò dá ọ lẹ́jọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti dá obìnrin tó ba ìgbeyàwó jẹ́, tí wọn sì ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀; Èmi yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ ìbínú àti owú mi wá sórí rẹ.

39 Nígbà náà ni èmi yóò fà ọ lé àwọn olólùfẹ́ rẹ lọ́wọ́, wọn yóò sì wó gbogbo òkìtì rẹ pẹ̀lú àwọn ojúbọ rẹ palẹ̀. Wọn yóò tú aṣọ kúrò lára rẹ̀, gbogbo ọ̀ṣọ́ rẹ ni wọn yóò gbà, wọn yóò sì fi ọ sílẹ̀ ní ìhòòhò àti ààbò.

40 Wọn yóò pe àjọ ènìyàn jọ lé ọ lórí, àwọn tí yóò sọ ọ́ ní òkúta, ti wọn yóò sì fi idà wọn gé ọ sí wẹ́wẹ́.

41 Wọn yóò jo gbogbo ilé rẹ palẹ̀ wọn yóò sì fi ìyà jẹ ọ́ ní ojú àwọn obìnrin. Èmi yóò fi òpin sí àgbèrè ṣíṣe rẹ. Ìwọ kò sì ní san owó fún àwọn olólùfẹ́ rẹ mọ́.

42 Nígbà náà ni ìbínú mi sí Ọ yóò rọ̀, owú ìbínú mi yóò sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ; inú mi yóò rọ, èmi kò sì ní bínú mọ́.

43 “ ‘Nítorí pé o kò rántí ọjọ́ èwe rẹ ṣùgbọ́n ìwọ ń rí mi fín pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ó dájú pé Èmi yóò mú gbogbo ohun tí ìwọ ti ṣe wa sórí rẹ, ni Olúwa Ọlọ́run wí, Ìwọ kì yóò sì ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yìí ni orí gbogbo ohun ìríra rẹ?

44 “ ‘Gbogbo àwọn to ń pòwe, ni yóò máa pòwe yìí mọ́ ọ pé: “Bí ìyá ṣe rí, bẹ́ẹ̀ni ọmọ rẹ̀ obìnrin.”

45 Ọmọ ìyà rẹ ni ọ lóòtọ́, to korìíra ọkọ rẹ àti àwọn ọmọ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ara ilé àwọn arábìnrin rẹ ni ọ nitootọ, àwọn to n korìíra ọkọ wọn sílẹ̀, tó tún ń korìíra àwọn ọmọ. Ará Híítì ni ìyá rẹ, baba rẹ si jẹ́ ara Ámórì.

46 Ẹ̀gbọ́n rẹ obìnrin ni Samaríà, òun àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ n gbé ni apá aríwá rẹ, Sódómù sì ni àbúrò rẹ, obìnrin tó ń gbé pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin rẹ ni ìhà gúúsù rẹ.

47 Kì í sẹ pé ìwọ rìn ni ọ̀nà wọn nìkan, tàbí ṣe àfiwé ìwà irira wọn ṣùgbọ́n ní àárin àkókò kúkúrú díẹ̀, ìwọ bàjẹ́ jù wọ́n lọ

48 Olúwa Ọlọ́run wí pé, Bí mo ṣe wà láàyè Sódómù tí í se ẹgbọ́n rẹ obìnrin àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ kò ṣe to ohun tí ìwọ àti ọmọbìnrin rẹ ṣe.

49 “ ‘Wò ó, ẹ̀sẹ̀ tí Sódómù ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin sẹ̀ nìyìí: Òun àti àwọn ọmọbìnrin rẹ gbéraga, wọ́n jẹ́ alájẹjù àti aláìbìkítà; wọn kò ran talákà àti aláìní lọ́wọ́

50 Nítorí náà, mo mu wọn kúrò níwájú mi lójú mi gẹ́gẹ́ bi iwọ ti ròó, nítorí ìgbéraga àti àwọn Ohun ìríra tí wọ́n ṣe.

51 Samaríà kò ṣe ìdájìn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Ìwọ ṣe àwọn ohun ìríra ju tirẹ̀ lọ, ìwọ sì jẹ kí àwọn arabìnrin rẹ dàbí olódodo pẹ̀lú gbogbo ìwọ̀nyí tí ìwọ ti ṣe.

52 Gba ìtìjú rẹ, nítorí ìwọ ti jẹ́ kí arábìnrin rẹ gba ìdáláre. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ti burú ju tí wọn lọ, wọn dàbí olódodo ju ìwọ lọ. Torí náà rú ìtíjú rẹ, kí o sì gba ẹ̀gàn rẹ pẹ̀lú nítorí ìwọ ti jẹ́ kí àwọn arábìnrin rẹ dàbí olódodo.

53 “ ‘Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Sódómù àti àwọn ọmọbìnrin rẹ padà ìgbèkùn àti Samaríà pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin rẹ, èmi yóò sì dá ìgbèkùn tirẹ̀ náà padà pẹ̀lú wọn

54 Kí ó bá à le rú ìtìjú rẹ, àti ẹ̀gàn gbogbo ohun tí ìwọ se láti tù wọ́n nínú.

55 Nígbà tí àwọn arábìnrin rẹ, Sódómù àti àwọn ọmọbìnrin rẹ; Samaríà àti àwọn ọmọbìnrin rẹ ba padà si ipò tí wọn wà tẹ́lẹ̀, ìgbà náà ni ìwọ náà yóò padà sí ipò àtijọ́ rẹ.

56 Iwọ ko tilẹ̀ ní dárúkọ arábìnrin rẹ Sódómù ni ọjọ́ ìgbéraga rẹ,

57 Kó tó di pé àsírí ìwà búburú rẹ tú síta, báyìí ìwọ di ẹni ẹ̀gàn lọ́dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Édómù Síríà àti gbogbo agbègbè rẹ àti lọ́dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Fílístínì àti lọ́dọ̀ àwọn tó yí ọ ká, ti wọn si ń kẹ́gàn rẹ.

58 Èmi yóò gba ẹ̀san ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti àwọn iṣẹ́ ìríra rẹ ní Olúwa wí.

59 “Báyìí ni Olúwa wí, ‘Èmi yóò hùwà sí ọ gẹ́gẹ́ bi ó ṣe tọ́ sí ọ, nítorí o ti kẹ́gàn ẹ̀jẹ́ nípa dídà májẹ̀mú.

60 Síbẹ̀ èmi yóò rántí májẹ̀mú tí mo bá ọ ṣe nígbà ewe rẹ, èmi yóò sì bá ọ dá májẹ̀mú láéláé.

61 Nígbà náà ni ìwọ yóò rántí àwọn ọ̀nà rẹ ojú yóò sì tì ọ́ nígbà tí mo bá gba àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò rẹ obìnrin padà: Fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọmọbìnrin, ṣùgbọ́n kì í ṣe lórí májẹ̀mú tí mo bá ọ dá.

62 Èmi yóò gbé májẹ̀mú mi kalẹ̀ pẹ̀lú rẹ, ìwọ yóò sì mọ pé èmi ni Olúwa.

63 Nígbà tí mo bá sì ti ṣe ètùtù fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tan, Èmi yóò sì rántí ojú yóò tì ọ́, ìwọ kò sì ní le ya ẹnu rẹ mọ́ nítorí ìtìjú rẹ, ni Olúwa Ọlọ́run wí.’ ”