Ísíkẹ́lì 29 BMY

Àsọtẹ́lẹ̀ Òdì Sí Éjíbítì

1 Ní ọjọ́ kejìlá, oṣù kẹ́wàá, ọdún kẹ́wàá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:

2 “Ọmọ ènìyàn, kọjú sí Fáráò ọba Éjíbítì kí ó sì sọ àṣọ̀tẹ́lẹ̀ sí i àti sí gbogbo Éjíbítì.

3 Sọ̀rọ̀, kí ó sì wí pé: ‘Báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Èmi lòdì sí ọ, Fáráò ọba Éjíbítììwọ dírágónì ńlá inú òkun tí ó dùbúlẹ̀ síàárin àwọn odò ṣíṣàn rẹèyí tí ó sọ wí pé, “Tèmi ni odò Náílì;èmi ni ó sì ṣe é fún ara mi.”

4 Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ìwọ̀ mú ẹnu rẹèmi yóò sì mú ẹja inú odò rẹgbogbo lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ.Èmi yóò fà ọ́ síta kúrò láàrin àwọn odò rẹ,àti gbogbo ẹja odò rẹ yóò lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ.

5 Èmi yóò sọ ọ́ nù sí ihàìwọ àti gbogbo ẹja inú odò rẹ:ìwọ yóò ṣubú sí gbangba okoa kì yóò sì ṣà ọ́ jọ tàbí gbé ọ sókè.Èmi ti fi ọ ṣe oùnjẹ fún àwọn ẹranko igbóàti fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run láti jẹ.

6 Nígbà náà gbogbo àwọn olùgbé ni Ijíbítì yóò mọ pé Èmi ni Olúwa.“ ‘Ìwọ ti jẹ́ ọ̀pá ìyè fún ilé Ísírẹ́lì.

7 Nígbà tí wọn fi ọwọ́ agbára wọn dì ọ́ mú. Ìwọ fọ́, ìwọ sì ya gbogbo èjìká wọn; nígbà tí wọn fi ara tì ọ́, ìwọ sẹ́, ìwọ sì mú gbogbo ẹ̀gbẹ́ wọn gbọ̀n.

8 “ ‘Nítorí náà, èyí yìí ní Olúwa Ọlọ́run wí: kéyèsí i Èmi yóò mú idà kan wá sórí rẹ tí yóò sì gé ènìyàn àti ẹran kúrò nínú rẹ.

9 Ilẹ̀ Éjíbítì yóò di ihà àti ahoro, nígbà náà ní wọn yóò sì mọ̀ wí pé èmi ní Olúwa.“ ‘Nítorí tí ìwọ wí pé, “Tèmi ni odò Náílì; Èmi ni mo ṣe é,”

10 Nítorí náà, mo lòdì sí ọ àti sí àwọn odò rẹ, èmi yóò sì mú kí ilẹ Éjíbítì di píparun àti ahoro, pátapáta, láti Mígídólì lọ dé Ásíwánì, dé ààlà ilẹ Kúṣì.

11 Kò sí ẹsẹ̀ ènìyàn tàbí tí ẹranko tí yóò gba ibẹ̀ kọjá; ẹni kankan kò ní gbé ibẹ̀ fún ogójì ọdún.

12 Èmi yóò sọ ilẹ Éjíbítì di ọ̀kan ní àárin àwọn ilẹ̀ tí ó di ahoro, fún ogójì ọdún, Èmi yóò sì fọ́n àwọn ara Éjíbítì ká sáàárin àwọn orílẹ̀ èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sáàárin gbogbo ilẹ̀.

13 “ ‘Ṣùgbọ́n báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí: Ní òpin ogójì ọdún, èmi yóò ṣa àwọn ará Éjíbítì jọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn níbi tí a fọ́n wọn ká sí.

14 Èmi yóò sì tún mú ìgbèkùn Éjíbítì padà bọ̀, èmi yóò sì dá wọn padà sí ilẹ̀ Pátírósì, ilẹ̀ àwọn baba ńlá wọn. Wọn yóò wà níbẹ̀ bí ìjọba tí a rẹ̀ sílẹ̀.

15 Ibẹ̀ yóò jẹ́ ìjọba tí ó rẹ̀lẹ̀ jùlọ nínú àwọn ìjọba, kì yóò sì gbé ara rẹ̀ ga mọ́ sórí àwọn orílẹ̀-èdè: nítorí èmi ni ó dín wọn kù, ti wọn kì yóò fi ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù mọ́.

16 Éjíbítì kí yóò sì jẹ orísun ìgbẹ́kẹ̀lé fún ilé Ísírẹ́lì mọ́ ṣùgbọ́n, yóò jẹ́ ìrántí fún àìṣedédé wọn, nígbà tí yóò bá wò wọ́n fún ìrànlọ́wọ́. Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run.’ ”

17 Ó sì ṣe ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kìn-ín-ní, ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:

18 “Ọmọ ènìyàn, Nebukadinésárì ọba Bábílónì mú kí ogun rẹ sin ìrú ńlá fún Tírè. Gbogbo ori pá, àti gbogbo èjìká bó, ṣíbẹ̀, òun àti àwọn ogun rẹ̀, kò rí owo ọ̀yà gbà láti Tírè fún wa, fún ìrú ti a ti sìn.

19 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Kíyèsí i, Èmi yóò fi Éjíbítì fún Nebukadinésárì ọba Bábílónì, òun yóò sì kó ọrọ̀ rẹ̀ lọ. Òun yóò bo ilé, yóò sì ṣe ìkógun ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ tí a san fún ológun rẹ̀.

20 Èmi ti fi Éjíbítì fún un gẹ́gẹ́ bí èrè wàhálà rẹ̀ nítorí òun àti àwọn ológun rẹ ṣe é fún mi, ni Olúwa Ọlọ́run wí.

21 “Ní ọjọ́ náà, èmi yóò mú kí ilé Ísírẹ́lì ní agbára, èmi yóò sì fún ọ ní ẹnu ọ̀rọ̀ ní àárin wọn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.”