Ísíkẹ́lì 38 BMY

Àsọtẹ́lẹ̀ Kan Sí Gógì

1 Ọrọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:

2 “Ọmọ ènìyàn, kọ ojú rẹ sí Gógì, ti ilẹ̀ Mágógì; olórí Roṣi, Méṣékì, àti Túbálì ṣọtẹ́lẹ̀ ní ìlòdì sí i

3 kí ó sì wí pé: ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi lòdì sí ọ, Ìwọ Gógì, olórí ọmọ Aládé Méṣékì àti Túbálì.

4 Èmi yóò yí ọ kiri, èmi yóò sì fi ìwọ̀ kọ́ ọ ní ẹnu, èmi yóò sì fà ọ́ jáde pẹ̀lú gbogbo ọmọ ogun rẹ, àwọn ẹṣin àti àwọn agẹsinjagun nínú ìhámọ́ra, àti ìpéjọ ńlá pẹ̀lú asà ogun ńlá àti kéékèèkéé, gbogbo wọn ń fi idà wọn.

5 Páṣíà, Kúsì àti Pútì yóò wà pẹ̀lú wọn, gbogbo wọn yóò wà pẹ̀lú asà àti ìsíborí wọn

6 Gómérì náà pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, àti Bẹti-Tógárímà láti jìnnàjìnnà àríwá pẹ̀lú gbogbo àwọn ọ̀wọ́ ogun rẹ̀-ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè pẹ̀lú rẹ̀.

7 “ ‘Múra sílẹ̀, múra tán, kí ìwọ àti gbogbo ìjọ náà péjọpọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí o sì pàṣẹ fún wọn.

8 Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, àwa yóò pè ọ́ fún àwọn ohun èlò ogun. Ní àwọn ọdún ọjọ́ iwájú ìwọ yóò dóti ilẹ̀ tí a ti gbà nígbà ogun, tí àwọn ènìyàn wọn kórajọ pọ̀ láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè sí àwọn òkè gíga ti Ísírẹ́lì, tí ó ti di ahoro fún ìgbà pípẹ́. A ti mú wọn jáde láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè, nísínsínyìí gbogbo wọn ń gbé ní àìléwu.

9 Ìwọ àti ọ̀wọ́ ogun rẹ àti ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè pẹ̀lú rẹ yóò gòkè, ẹ̀yin yóò tẹ̀ṣíwájú bí ìjì; ìwọ yóò dàbí ìkùùkuu tí ó bo ìlẹ̀ mọ́lẹ̀.

10 “ ‘Èyí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Ní ọjọ́ náà èrò kan yóò wá ṣọ́kan rẹ, ìwọ yóò sì pète ìlànà búbúru.

11 Ìwọ yóò wí pé, “Èmi yóò gbé Ogun ti ilẹ̀ àwọn tí a kò fi odi yíká: Èmi yóò gbé ogun ti àwọn ènìyàn àlàáfíà tí a kò furasí-gbogbo wọn ń gbé ní àìsí odi, ní àìsí ẹnu ọ̀nà òde àti àsígbà.

12 Èmi yóò mú ohun ọdẹ, èmi yóò sì kó ìkógun, èmi yóò sì yí ọwọ́ mi padà sí ibi ìwólulẹ̀ ti a ti tún kọ́, àwọn ènìyàn tí a kójọpọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè, tí ó ní ọrọ̀ nínú nǹkan ọ̀sìn àti ẹrú, tí ó ń gbé ní àárin gbùngbùn ilẹ̀ náà.”

13 Ṣébà, Dédánì àti àwọn oníṣòwò Táṣíṣì àti gbogbo ìletò rẹ yóò sọ fún un yín pé, “Ṣé ẹ̀yin wá fún ìkógun? Ṣé ẹ̀yin ti kó àwọn ìjọ yín jọpọ̀ fún ìkógun, láti kó silífà àti wúrà lọ, láti kó nǹkan ọ̀sìn àti ẹrú àti láti gba ọ̀pọ̀ ìkógun?” ’

14 “Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, ṣọtẹ́lẹ̀ kí ó sì ṣọ fún Gógì: ‘Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Ní ọjọ́ náà, nígbà tí àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì ń gbé ní àìléwu, ìwọ kì yóò ha ṣe àkíyèsí rẹ̀?

15 Ìwọ yóò wá láti ààyè rẹ ní jìnnàjìnnà àríwá, ìwọ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè pẹ̀lú rẹ, gbogbo wọn yóò sì gun ẹsìn ìjọ ńlá, jagunjagun alágbára.

16 Ìwọ yóò tẹ̀síwájú ní ìlòdì sí àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bí ìkùùkuu tí ó bo ilẹ̀. Ni àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀, ìwọ Gógì, èmi yóò mú ọ wá ní ìlòdì sí ilẹ̀ mi, kí àwọn orílẹ̀ èdè lè mọ̀ mi nígbà tí mo bá fí ara hàn ni mímọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ ní ojú wọn.

17 “ ‘Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Ìwọ ha kọ́ ni mo ṣọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ìgbà ìṣáájú láti ẹnu àwọn ìránṣẹ́ mi ti Ísírẹ́lì? Ní ìgbà náà wọ́n ṣọtẹ́lẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún pé èmi yóò mú ọ lòdì sí wọn.

18 Èyí ni ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ náà: Nígbà tí Gógì bá kọlu ilẹ̀ Ísírẹ́lì, gbígbóná ibínú mi yóò ru sókè, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

19 Ní ìtara mi àti ní gbígbóná ìbínú mi, Mo tẹnumọ́-ọn pé; ní àsìkò náà ilẹ̀ mímì tíi ó lágbára ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì yóò ṣẹlẹ̀.

20 Ẹja inú òkun, àwọn ẹyẹ òfuurufú, àwọn ẹranko igbó, àti gbogbo ẹ̀dá tí ó ń rìn lórí ilẹ̀ yóò wárìrì fún ìfarahàn mi. A óò yí òkè gíga po, àwọn bèbè òkúta ni àwa yóò fọ́ sí wẹ́wẹ́, gbogbo ògiri ni yóò wó palẹ̀.

21 Èmi yóò fa idà yọ ni ìlòdì sí Gógì ní orí gbogbo àwọn òkè gíga mi ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. Idà gbogbo ènìyàn yóò lòdì sí arákùnrin rẹ̀.

22 Èmi yóò gbé ìdájọ́ mi jáde lórí rẹ̀ pẹ̀lú ìyọnu àti ìtàjẹ̀sílẹ̀; Èmi yóò dá àgbàrá òjò, òkúta yìnyín àti imí ọjọ́ tí ń jó lé e lórí àti lórí ọ̀wọ́ ogun àti lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè pẹ̀lú rẹ̀.

23 Nítorí náà, Èmi yóò fi títóbi mi àti ìjẹ́-mímọ́ mi hàn, Èmi yóò sì fi ara mi hàn ní ojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’